Àwọn olówó Naijiria 5 tí owó wọn ju owó ìsúnná Naijiria lọ!

Oríṣun àwòrán, Google
Olowo marun un lorilẹ-ede Naijiria ni owo to to san owo isunna lorilẹ-ede Naijiria.
Iwadii ti ile-isẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Oxfam gbe jade lo fihan wi pe owo awọn olowo yii le ni biliọnu mọkanlelọgbọn owo ilẹ okeere dọla.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eleyii jẹ iye oju owo fun owo isunna Naijiria ni ọdun 2017, triliọnu meje naira o le ni o ma a jẹ iye owo Naijiria.
Orukọ awọn marun un ti iwe iroyin Forbes gbe jade pe wọn ni owo julọ ni orilẹ-ede Naijiria ni:
- Aliko Dangote
- Mike Adenuga
- Abdul Samad Rabiu
- Folorunsho Alakija
- Femi Otedola
Amọ iwadii naa ni ida ọgọta awọn ọmọ Naijiria ni ko ni to miliọnu dọla kan lati na loojọ, eleyii to fi han gbangba iru iya ati isẹ to n jẹ ọpọlọpọ awọn ara orilẹ-ede Naijiria
Bakan naa ni iwadii Oxfam gbe jade ni ọpọlọpọ awọn eniyan ni orilẹ-ede Naijiria ni isẹ ati iya n ba finra.
Oxfam fi kun wi pe pẹlu u bi Naijiria se jẹ orilẹ-ede to n pese epo rọbi julọ ni ilẹ Afirika, ko ye ki wọn jiya amọ iwa ibajẹ ati jẹgudujẹra lo n fa ifaseyin fun awọn araalu.










