Minimum wage: Buhari ti buwọ́lu sísan ẹ̀kúnwó oṣù tuntun fáwọn òṣìṣẹ́ àpapọ̀

Awọn ero ni popo fun iwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin ayọ sọkalẹ fawọn oṣiṣẹ bayii paapaa awọn ti wọn ko gba ju ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lọ tẹlẹ.

Idi iroyin ayọ yii ko yẹ lori bi aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe buwọlu sisan owo oṣu tuntun naa fun awsn oṣiṣẹ apapọ ti owo ti wọn n gba ko to iye ẹkunwo oṣu tuntun naa lọwọ yii.

Alaga ajọ to n mojuto agbekalẹ owo oṣu lorilẹ-ede Naijiria, Richard Egbule ṣalaye pé igbesẹ naa bẹrẹ lẹyẹ o sọko.

O sọ fawọn oniroyin nilu Abuja pe ileeṣẹ oluṣiro owo agba Naijiria ni yoo buwọlu owo naa bayii ni ibamu pẹlu asiko ti aarẹ fọwọ si sisan rẹ.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ẹ lọ mú ẹ̀rí ibi tí a ti gba owó wá- NLC/TUC

Gẹgẹ bi ọgbẹni Egbule ti ṣe sọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin ọdun 2019 ni sisan owo oṣu naa bẹrẹ ifidimulẹ; afẹfẹ rẹ yoo si kan awọn onipele owo oṣu marun un.

Awọn ti ọrọ naa kan ni awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ to wa lori (CONPSS), awọn oṣiṣẹ eto ilera to wa lori ilana owo osu (CONHESS), awọn oṣiṣẹ ẹka miran to wa lori ilana owo osu (CONRAISS).

Àkọlé fọ́nrán ohùn, ọ̀rọ̀ lórí ọkọ̀ fún Fayose

Bakan naa lo kan awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ giga to wa lori ilana owo osu (CONTISS II) ati (CONTEDISS).

Amoṣa o ni ijiroro ṣi n tẹsiwaju lori awọn ato ti yoo kan awọn oṣiṣẹ ti owo oṣu wọn ju ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lọ.

Àkọlé fídíò, Mo fi iṣẹ́ Banki silẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ alápatà - Derin