Minimum Wage: Saraki dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ fún sùúrù wọn lórí owó oṣù tuntun

Bukola Saraki duro niwaju ile igbimọ Aṣofin agba Naijria.

Oríṣun àwòrán, Senate President

Ile Igbimọ Aṣofin Agba orilẹede Naijira ti bu ọwọ lu abadofin kan to ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni yoo jẹ owo oṣu to kere ju ni orilẹede yii.

Alaga Igbimọ tẹẹkoto lori ijiroro ọrọ owo oṣu naa, Sẹnetọ Francis Alimikhena, lo ka abajade ijiroro igbimọ naa niwaju ile.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Bukola Saraki yin awọn ọmọ igbimọ naa, o si tun dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ Naijiria àti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ fun suuru wọn lori ọrọ naa.

O ni, "Mo fi da yin loju wipe ijọba ko ni duro fun iyanṣẹlodi ki a to ṣe oun to dara fun ara ilu. Mo lero wipe owo oṣu to kere ju tuntun yii yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ jara moṣẹ daradara si."

Awon Osisẹ
Àkọlé àwòrán, Minimum Wage: Ilé ìgbìmọ asofin dájọ ti sísan yóó bẹ̀rẹ̀

Ọsẹ to kọja ni Saraki yàn ìgbákeji ọmọ ilé tó pọ̀jù lọ, Sẹnatọ Francis Alimikhena, gẹ́gẹ́ bii adelé olórí ìgbìmọ náà, lẹ̀yìn ti alága ti wọn yan Sẹnatọ Olusola Adeyeye yọ aara rẹ kurò, pelú àlàyé pé òun ni àìlera.

Àkọlé fídíò, Collapsed Building: Ayálégbé ló dára bí ìjọba ṣe wólé àmọ́ wọ́n fẹ́ ìrànwọ́ ilé míràn

Nigba naa, Alimikhena fí ọkan àwọn ọmọ Nàìjíríà balẹ̀ pé ìgbìmọ̀ náà yóò múṣẹ́ ṣe ni wàràńṣesaà láti mu àbájade to ni ìtumọ lọ́sẹ̀ tó ń bọ

Ọkan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà Sẹnatọ Solomon Adeola pe àwọn yóò ṣe àtúngbéyẹ̀wò snà ti wọn ń gbà pín owó sí ìpínlẹ̀ lójúnà àti sàn ẹgbẹ̀rún náírà gẹ́gẹ́ bi owó òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ jákejádò ẹka ìjọba

Adeola faramọ àgbékalẹ̀ tó wà nínú àbádofin owó òṣìṣẹ́ tó kére jùlọ, ó fi kun pé ti ilé ìgbìmọ fẹ́nukò pé gbogbo ìpele ìjọba ló gbodo san owo náà.