Election 2019 Updates: Makinde ní Ajimọbi fẹ́ ná owó Ọyọ tán, láti dá ìjọba òun lóró

Gomina to ń bọ̀ lọna ni Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ní ẹru n ba oun lori bi Gomina Abiola Ajimobi ṣe n na owo lẹnu ọjọ mẹta yii.
Makinde ni, ṣe ni Ajimọbi n fa owo yọ lapo ijọba bi nkan miiran nibayii ti ọjọ ti yoo fipo gomina silẹ, May 29, se n sunmọ ile.
Ṣugbọn gomina Ajimọbi ti wa fesi pada pe, oun to ba wu ẹlẹnu lo le fi ẹnu rẹ sọ, nitori pe, oun ṣi ni di ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Karun-un ọdun 2019 lati ṣe ijọba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Kọmiṣọna fun eto iroyin ati aṣa nipinlẹ Ọyọ, Toye Arulogun to gbẹnusọ gomina sọrọ ni, Ajimobi ko le ka ọwọ gbera, maa wo ilu niran titi ti ọjọ ti yoo kuro nipo yoo fi pe.
Makinde ni ṣe ni Ajimọba fẹ da ijọba oun to n bọ loro, ko ma baa ṣeeṣe ki oun ri nkan ṣe.
O tọka si pe miliọnu kan aabọ ni gomina fun ijọba ibilẹ kọọkan, ti gbogbo wọn jẹ metalelọgbọn to wa ni ipinlẹ naa, lati fi ṣe awọn iṣẹ amuṣe kan.
Gomina to n bọ naa tun ni, Ajimọbi tun fun ajọ to n tun opopona ṣe ni ipinlẹ Ọyọ, ni bii biliọnu marun-un naira.
Makinde ni oun ati awọn to n ba oun ṣiṣẹ n ṣọ owo to wa ninu apo ijọba ati wipe, oun yoo gbe igbesẹ lati ṣe oun to yẹ ni kete ti wọn ba bura fun ou tan.














