Olè Lekki: Obìnrin méjì ni wọ́n dá lọ́nà, tọ́wọ́ ọlọ́pàá fi tẹ̀ wọ́n

Awọn adigunjale to gbe ibọn soke

Oríṣun àwòrán, @policeNG

Yoruba ni ọjọ gbogbo ni ti ole, amọ ọjọ kansoso pere ni ti olohun.

Bẹẹ lọrọ ri fun awọn ole meji kan nipinlẹ Eko, nigba ti ọwọ palaba wọn segi, ti akara wọn si tu sepo.

Awọn firi nidi ọkẹ naa, ti wọn gbajugbaja fun isẹ alọnilọwọgba lagbegbe Lekki, ni wọn pe oruk wọn ni Adebayọ Ayọmide ati Isaac David.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aago mẹsan alẹ ni ikọ ọtẹlẹmuyẹ, ti ọga ọlọpa kan lati agọ ọlọpa Marọkọ, Isah Abdulmajid ko sodi, lọ paraaro afara kan to so adugbo Lekki pọ mọ Ikoyi, asiko yii si ni wọn ri awọn omidan meji kan, ti wọn n gbọn jinni-jinni.

Nigba ti wọn beere lọwọ awọn ọmge naa pe, ki lo se wọn, ni wn ba salaye pe awọn alọkolohunkigbe meji lo fi ibọn gba ohun ini awọn, ti wọn si tọka ọna tawọn ole ọhun morile fun awọn ọlọpa.

Àkọlé fídíò, Aṣọ òkè: Alákọ̀wé ní ọ̀nà láti wá oúnjẹ fáwọn tó ń ṣe aṣọ òkè ló ṣún òun débẹ̀

Ọwọ sinkun awn ọlọpa yii ba awọn ole naa, ti wọn si ba ibọn ilewọ kan, ada ati ọpọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ alagbeka lọwọ wọn.

Nigba ti wọn n ka ni agọ ọlọpaa, awọn ole naa ni ara ọmọ ẹgbẹ ikọ adigunjale kan ti wọn n da agbegbe Lekki laamu ni awọn.

Ibọn ti wọn na soke

Oríṣun àwòrán, @WeArePindula

Nigba to n gbosuba fun ikọ ọlọpa to se bẹbẹ yii, Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Eko, Zubairu Muazu wa pasẹ pe ki wọn gbe ẹsun awọn ole meji ọhun sabẹ ikọ to n gbogun ti iwa idigunjale nipinlẹ Eko fun iwadi kikun.

Muazu wa fọkan awọn olugbe ipinlẹ Eko balẹ pe ileesẹ ọlọpa mu aabo ẹmi ati dukia wọn lọkunkundun, to si tun fewe ọmọ mọ awọn ọdaran leti lati tun ero wọn pa, bibẹẹkọ ikoko ko ni gba omi, ko gba ẹyin, ko tun gba ṣọṣọ.