Election Update 2019: Iléeṣẹ́ ológunní Wike gbówó ńlá fáwọn láti da ìbò rú

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti fẹsun kan gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike pe o gbiyanju lati fi owo ra awọn ọmọ ogun lasiko idibo to waye nipinlẹ Rivers.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun fi sita, wọn ni Gomina Wike gbe owo banta-banta lọ fun awọn ọmọ ogun Ẹkun kẹfa ileesẹ ologun, lati da eto idibo ru fun anfaani ara a rẹ, to si tun n fi ẹsun ṣiṣe ègbè kan awọn ọga ileeṣẹ ologun.
Wọn fi ẹsun kan pe awọn oluranlọwọ fun Wike gbe owo lọ si ọgba banki apapọ Naijiria to wa nilu Port Harcourt gẹgẹ bi owo ẹyin fun awọn ọmọ ogun to wa nibẹ lọjọ kẹtalelogun oṣu Keji, ti i ṣe ọjọ idibo.
Awọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kíni ìwọ mọ̀ nípa Funmilayọ Ransome-Kuti?
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
- Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa ‘Ajala Travels’?
- Wòlíì Kasali ní Dolapo Awosika kò lé ìyàwó òun jáde
- 'Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ'
- Ṣẹ gbọ́ nípa Alájọ Ṣómólú, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
Ninu ayẹwo ileesẹ ologun lo ti farahan pe, Ọgagun kan, AP Ubah ati awọn ọlọpaa mẹta; DSP Oyoku Ifelle, Inspẹkitọ Hycent Oboi ati Sajẹnti Nketan Chuks ati Akanu Garba, gba owo ẹyin lọwọ awọn oluranlọwọ Gomina Wike.
Lara ohun ti wọn ba lọwọ wọn bi ẹri ni miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna ọtalerugba o din mẹwa Naira ti wọn ba ninu ọkọ DSP ọlọpaa naa.
Bakan naa ni wọn ba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ninu ọkọ ayọkẹlẹ Ọgagun AP Ubah.

Oríṣun àwòrán, @Gov_Wike
Oun paapa si jẹwọ pe awọn oluranlọwọ Gomina Wike lo fun oun ni owo naa pẹlu ileri ile to jọju fun, lasiko ti yoo fi wa ni ipinlẹ naa.
Awọn nkan mi i tawọn ologun tun ri ni kaadi pelebe ajọ INEC mẹẹrin, ati awọn apo iwe to jẹ ti ile ijọba ipinlẹ Rivers.
Sugbọn, lọsan ọjọ Iṣẹgun, ileesẹ ologun nibi ipade oniroyin to ṣe, tun fi awọn eniyan kan han, pẹlu ẹsun pe wọn se mago-mago ibo.
Bo tilẹ jẹ wi pe awọn ti wọn fi ẹsun kan sọ pe bẹẹkọ.












