2019 elections: APC gba ìjòkò tó pọ̀ jùlọ ní ilé aṣòfin àgbà

Oríṣun àwòrán, Senate Nigeria
Ẹgbẹ oṣelu APC lo ni ijoko to pọ julọ bayii fun ile aṣofin agba ni saa iṣejọba to n bọ.
Lasiko idibo apapọ to waye ni ọjs kẹtalelogun oṣu keji ọdun 2019, ijoko mejilelọgọta ni APC ri gbamu ninu ijoko mọkandinlaadọfa, 109 to wa ni ile aṣofin agba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni mẹtadinlogoji ti ẹgbẹ oṣelu YPP si di ijoko kan ṣoṣo mu.
Bi o tilẹ jẹ pe ijoko mọkandinlaadọfa lo wa ni ile aṣofin agba ijoko ọgọrun ṣi ni ajọ INEC kede ti o si ti paṣẹ atundi ibo lawọn ipinlẹ kan.
Ni ọjọ kẹsan oṣu kẹta atundi ibo waye lawọn ẹkun idibo bii Abia South, Imo West ati North, Kogi East, Ondo South, Plateau South, Rivers East, Rivers West.
Lọwọ yii wọn n reti idajs ile ẹjọ lori ẹkun idibo Bauchi south.
Ninu awọn ọgọrun ijoko ti wọn ti kede, obinrin mẹfa ti wa ninu wọn.








