Nigeria Elections Updates: Àkójọpọ̀ orúkọ àwọn tí yóò gbàwé ẹ̀rí mo yege rèé

DDD

Oríṣun àwòrán, DDD

Àkọlé àwòrán, SSS

Ajọ eleto idibo nil Naijiria, INEC, ti kede pe Ọ̀jọbọ, ọjọ Kẹrinla osu kẹta ọdun yii ni awọn eeyan to yege ibo sile asofin apapọ yoo gba iwe ẹri Mo yege.

Ikede kan ti INEC fi soju opo ayelujara rẹ wa fewe ọmọ mọ awọn oludije ti orukọ wọn ko ba si ninu akọsilẹ awọn eeyan to yege ibo sile asofin apapọ, eyiti INEC fi sita, lati mase yọju si ibudo ti wọn yoo ti pin iwe ẹri naa.

Ohun to wa ya ni lẹnu julọ ni pe orukọ gomina ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha ti INEC kede pe o yege ninu idibo sile asofin agba ni orukọ rẹ ko si lara awọn orukọ ti ajọ INEC kede pe yoo gba iwe ẹri mo yege.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n salaye idi ti orukọ gomina Okorocha fi sọnu ninu orukọ awọn eeyan to yege ibo sile asofin agba, Inec salaye pe agidi ni Okorocha lo lati fi yege ibo naa, ti ko si jẹ ki ibo naa lọ nirọwọ rọsẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, lasiko ti wọn ka esi ibo sile asofin agba ni ipinlẹ Imo, ni osisẹ agba fun ajọ eleto idibo, to yẹ ko jabọ esi ibo naa ti kede pe, se ni wn ko ohun ni papamọra lati kede ayederu esi idibo, kii si se ojulowo esi ibo lo wa ni akọsilẹ oun.

Ile asofin apapọ

Oríṣun àwòrán, @NationaAssembly

Wayi o, lọwọlọwọ bayii, orukọ eeyan ọgọrun ni INEC gbe sita pe o yege ibo sile asofin agba, ninu asofin agba mọkandinlaadọfa to yẹ ko wa nibẹ.

Ninu ọgọrun Sẹnetọ tuntun naa, ẹgbẹ oselu APC ni ijoko mejilelọgọta nigbati PDP ni mẹtadinlogoji, ti YPP si ni ẹyọ kansoso pere.

Eyi ni awọn orukọ ti INEC fisita lati wa gba iwe ẹri Mo yege:

Akọsilẹ orukọ awọn to yege ibo sile asofin agba

Oríṣun àwòrán, Inec

Akọsilẹ orukọ awọn to yege ibo sile asofin agba

Oríṣun àwòrán, Inec

Akọsilẹ orukọ awọn to yege ibo sile asofin agba

Oríṣun àwòrán, Inec

Akọsilẹ orukọ awọn to yege ibo sile asofin agba

Oríṣun àwòrán, Nec

Akọsilẹ orukọ awọn to yege ibo sile asofin agba

Oríṣun àwòrán, Inec

Akọsilẹ orukọ awọn to yege ibo sile asofin agba

Oríṣun àwòrán, Inec

Akọsilẹ orukọ awọn to yege ibo sile asofin agba

Oríṣun àwòrán, Inec