Governorship election update: PDP ní ẹgbẹ́ òun ló ń mókè láwọ̀n ìpínlẹ̀ tí ìbò kó ti parí

Oríṣun àwòrán, InEC
Ẹgbẹ oṣelu alako PDP ti sọ pe, eru ati jibiti ni ajọ eleto idibo INEC fẹ ṣe lẹyin ti ajọ naa kede wi pe, eto idibo gomina nipinlẹ mẹfa kaakiri orilẹede Naijiria ko tii yanju.
Ajọ INEC kede lọjọ Aje pe idibo gomina ni ipinlẹ Kano, Sokoto, Benue, Bauchi, Adamawa ati Plateau ko tii kẹsẹ jari.
Igba akọkọ re e ti irufẹ iṣẹlẹ yii yoo waye lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada si ijọba awarawa lọdun 1999.
Ajọ INEC tiẹ ti kọkọ so eto idibo gomina nipinlẹ Rivers rọ nitori laasigbo to n ṣẹlẹ nipinlẹ naa.
Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu PDP fẹsun kan alaga ajọ INEC Ọjọgbọn Mamood Yakubu pe, ohun ti ẹgbẹ APC ni ki o ṣe, gan an lo n ṣe.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
PDP ni ẹgbẹ awọn lo n leke nigbogbo ipinlẹ mẹfẹẹfa ti INEC ti ni eto idibo gomina ko tii yanju.
Alukoro fẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Kola Ologbondiyan to bawọn oniroyin sọrọ lọjọ Aje l'Abuja sọ pe ẹgbẹ naa ti ri aṣiri pe, ile iṣẹ aarẹ lo dari ajọ INEC.









