2019 elections: INEC ní òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó sá lọ kò ní gbowó iṣẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria
Ajọ INEC ti sọ pe ko si owo fun alamojuto idibo to fi ẹsẹ fẹẹ ni ipinlẹ Cross River lasiko idibo gomina ati aṣofin ipinlẹ naa.
Kọmiṣọna fun ajọ INEC ni ipinlẹ Cross Rivers, Ọmọwe Frankland Briyai lo sọ bẹẹ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Calabar.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwòdamiẹnu àwòrán rèé nílé àwọn olùdíje tó wọ́lé ìbò
- Governorship Election Results: Àgbùnbánirọ̀ tó bá INEC ṣiṣẹ́ kú nínú ìjàmbà ọkọ̀ ojú omi l'Ondo
- Lẹ́yìn tórí yọọ́ nínú ìjambà ọkọ̀; Ọ̀jọ̀gbọ̀n Pius Adesanmi kú nínú ìjàmbá bàálù Ethiopia!
- Gómìnà tí wọ́n yàn ní Kwara, Abdulrazaq ní òun yóò tú ìdigunjalè Offa yẹ̀wò
O ni alamojuto idibo ti a n sọrọ rẹ yii lo yẹ ko dari eto idibo ni ijọba ibilẹ guusu Calabar ki wọn to ṣadede rii pe o ti di awati.
O ni lootọ oun mọ idi ti o fi fi ẹsẹ rẹ fẹẹ amọ ṣa eyi ko ṣe ipalara fun eto idibo naa rara.
Kọmiṣọna ajọ INEC naa ṣalaye fawọn oniroyin pe inu oun dun pe idibo naa lọ ni irọwọ irọsẹ.
Ninu esi idibo ti ajọ INEC gbe jade ni ipinlẹ Cross River, PDP lo bori pẹlu ibo 381,484, oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC John Owan-Enoh ni 131,161.












