Pius Adesanmi: Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ń dárò ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ Nàìjíríà tó kú nínú ìjàmbá bàálù Ethiopia

pius

Oríṣun àwòrán, @pius

Àkọlé àwòrán, Ko sẹni ti kò ni ku laye!
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iku doro, iku sẹka. Iku mu ẹni re lọ.

Ọgọọrọ ọmọ orilẹ-ede Naijiria lo ṣedaro Ọjọgbọn Pius Adesanmi to wa lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba baalu Ethiopia to ja lulẹ lọna Nairobi.

Adesanmi n lọ fun ipade ajọ ilẹ Afirika ni Nairobi ko to ṣagbako iku ojiji ninu ijamba baalu ọhun.

Ta ni Ọjọgbọn Pius Adesanmi gan an?

Ọjọgbọn Adesanmi lọ sile iwe Titcombe College niluu Egbe, bẹẹ lo tun kawe ni ile iwe giga fasiti ti ilu ijọba apapọ ni Ilorin, nipinlẹ Kwara nibi to ti gboye ninu ẹkọ ede Faranse.

Pius Adesanmi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Pius Adesanmi

Àkọlé àwòrán, Iku mu Pius Adesanmi lọ

O tun tẹsiwaju nigba to gboye miran ninu ẹkọ ede Faranse ni fasiti ilu Ibadan.

Ọjọgbọn Adesanmi tun kẹkọọ ni fasiti British Columbia niluu Vancouver lorilẹ-ede Canada.

Pius Adesanmi

Oríṣun àwòrán, Twitter/Pius Adeasanmi

Àkọlé àwòrán, Iku mu Pius Adesanmi lọ

Adesanmi jẹ Ọjọgbọn ninu ede oyinbo ni fasiti Carleton nibi to ti n ṣiṣẹ ki ọlọjọ to de gẹgẹ bi oludari ẹkọ nipa ilẹ Afirika.

Iroyin kan sọ pe ọmọ orilẹ-ede Canada mẹjọ lo wa ninu ijamba baalu ọhun.

Pius Adesanmi

Oríṣun àwòrán, @pius

Àkọlé àwòrán, Ojogbon to mọ oyun inu ikarahun igbin ninu imọ aṣa ilẹ Adulawọ

Nitori naa o ṣeeṣe ko jẹ pe wọn ka Ọjọgbọn Adesanmi mọ awọn ọmọ Canada to ku ninu iṣẹlẹ ọhun nitori fọto rẹ to wa loju opo Facebook rẹ gan fihan pe iwe irinna rẹ si wa lọwọ rẹ nigba to wa ni papakọ ofurufu lọjọ Abamẹta.

Awọn awada to sọ bi ọrọ to kẹyin lori opo Twitter rẹ re e.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Ojọgbọn Pius Adesanmi kagbako ninu ijamba ọkọ to waye ni oṣu keje, ọdun 2018.

Eyi ṣẹlẹ nigba ti o n rinrin ajo ni ipinlẹ Ọyọ nigba to wa si Naijiria.

oko

Oríṣun àwòrán, saharareporter

Àkọlé àwòrán, ọkọ ti ọjọgbọn Pius ti fi kọkọ ni ijamba ọkọ

Nigba ti BBC kan si awọn eniyan to mọọ daadaa bii akọwe fun gomina nile ijọba ipinlẹ Kogi, Petra Akiti-Oyegbule, ẹkun ni wọn bu si lori aago.

Ojọgbọn Naijiria miran naa ṣalaisi ninu ijamba ọkọ ofurufu ọhun

Ohun ti a tun gbọ ni pe Ọjọgbọn Abiọbun Bashua wa lara awọn ọmọ Naijiria to lugbadi iku ojiji ninu iṣẹlẹ baalu Ethiopia naa.

Ọjọgbọn Bashua ti ṣiṣẹ pẹlu ajọ iṣọkan agbaye gẹgẹ bi oludari ikọ to n ṣoju ajọ naa (UNAMID) ọdun 2015 lo fipo naa silẹ.

Aworan to ya kẹyin nigba to dipo naa mu re e.

Abiodun Bashua

Oríṣun àwòrán, Twitter/Abiodun Bashua

Àkọlé àwòrán, Iku pa ọjọgbọn meji ọmọ Naijiria

Opolopo awọn eniyan lo ti n ṣọfọ ọjọgbọn Bashua lori ayelujara.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

Ki Ọlọrun dẹlẹ fun awọn eni rere, ọjọgbọn kikun to re iwalẹ àṣà.