Sugar: Ilé ìwòsàn UCH ló dákẹ́ sí torí ọgbẹ́ ọta ìbọn

Oríṣun àwòrán, Temitope Sugar
Ọmọ agboole Efungade-Onigbodogi, Alafara Oje ni ijọba ibilẹ Ibadan North East ni ipinlẹ Ọyọ, ni Ọlatoye Temitọpẹ ti ọpọ mọ si Sugar.
Onigbodogi ati Alape ni ọlọkọ to wa Temitọpẹ wa sile aye lọdun 1973, ṣe wọn ni ọmọ Ibadan ti ko ba ni agboole ati oko kii ṣe ojulowo ọmọ Ibadan.
Ileewe alakọbẹẹrẹ St Michael Primary School, Yemetu ati I.M.G Primary School, Beyerunka, Alafara Oje ni Temitọpẹ lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lẹyin naa lo gba ileewe girama Ikolaba Grammar School, St Luke's College, Molete ati Alugbo Comprehensive High School, Egbeda lọ, ti gbogbo rẹ ni ilu Ibadan.
Sugar gba iwe ẹri olukọni onipo kini ni ileewe ẹkọṣẹ olukọni NCE Federal College of Education, to wa ni Osiẹlẹ nilu Abeokuta, ipinlẹ Ogun, ki o to lọ si ileewe giga fasiti Ibadan lati gba iwe ẹri imọ ijinlẹ akọkọ, B.Sc, ati iwe ẹri imọ ijinlẹ keji.

Oríṣun àwòrán, Temitope olatoye
Kansilọ ni ijọba ibilẹ Ọdẹda lo fi bẹrẹ irinajo oṣelu rẹ. Wọn yan an gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ fun ijọba ipinlẹ Ogun lasiko iṣejọba Ọtunba Gbenga Daniel.
Lẹyin to ti jẹ olori ẹka ọdọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹkun idibo apapọ aringbungbun ipinlẹ Ogun, lo wa lọ du ipo alaga ijọba ibilẹ Lagelu ni ipinlẹ Ọyọ ni ọdun 2007.

Oríṣun àwòrán, olatoye sugar
Ni ọdun 2011, ni wọn fi ibo yan an si ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Accord, ki o to wọle gẹgẹ bii ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin to n soju ẹkun idibo Lagelu/Akinyele, labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC.
Ni ọdun 2018 lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADP lati du ipo Sẹnetọ ki o to fidirẹmi.
Ile iwosan nla UCH ni ilu Ibadan lo ku si ni ọjọ kẹsan oṣu kẹta ọdun 2019, lẹyin ti o fara gba ọta ibọn ni agbegbe Lalupọn lasiko idibo sipo gomina to waye nibẹ.












