2019 elections: Ilé iṣẹ́ ológun ní ìwé òfin Nàìjíríà fàyè sílẹ̀ fáwọn láti wà níta fún àmójútó ìdìbò

ikọ ologun laaarin igboro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ ologun ni iwe ofin Naijiria faye gba wọn ninu eto idibo

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti sọ wi pe awọn ko ṣe ayọjuran si eto idi idibo to n lọ lọwọ lorilẹede Naijiria.

Olu ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ṣalaye fun awọn akọroyin lọjọ ẹti pe atilẹyin fun awọn ọlọpaa ni ojuṣe ti wọn yan fun awọn ninu eto idibo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alukoro fun ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹede Naijiria. Onyema nwachukwu ni ojuṣe yii wa ni ibamu pẹlu ilakalẹ abala iwe ofin ọdun 1999.

Abala ikọkanlelaadọrin o le igba 271 iwe ofin ọdun 1999 naa ṣalaye pe a lee ko awọn ọmọogun sita "lati ran awọn ọlọpaa lọwọ lasiko idibo"

Amọ ṣa, o ni ninu ṣiṣe ojuṣe yii ilana gbogbo wa fun awọn ọmọogun lati tẹle ki wọn maa baa kọja aye wọn.

Awọn ikọ ologun kan laaarin igboro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria tun sọ wi pe ọmọogun kankan ko gbọdọ wọ aṣọ ogun lọ si ibudo idibo kankan

O ni yatọ si eyi awọn ọmọogun naa lẹtọ lati dibo, ṣugbọn ko si eyikeyi wọn to gbọdọ wọ aṣọ iṣẹ wọn lọ si ibudo idibo.

Bakan naa lo tun fi ọkan araalu balẹ pe, awọn ologun ko nii lọkan lati gbẹsan lori awọn ọmọogun ti awọn janduku kan kọlu lasiko idibo aarẹ to waye laipẹ yii.