2019 elections: Ganduje ní òun yóò gba èsì yóòwù tó bá jáde ní ìdìbò gómìnà Kano

Oríṣun àwòrán, kabiru gaya
Gomina ipinlẹ kano, Abdullahi Ganduje ti ṣalaye ohun ti yoo ṣe bi okete ba padi ọrẹ da fun ninu idibo gomina ọjọ satide.
Ganduje ni ko si meni meji fun oun bi oun ba fidirẹmi ninu idibo naa ju pe ki oun ki ẹni to ba bori ku oriire.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gomina Ganduje sọ eyi di mimọ lasiko ti o fi n tọwọ bọwe adehun alaafia ni ilu Kano.
Gomina ipinlẹ Kano ọhun ni oun to ye oun ni pe Ọlọrun nii fi ọba jẹ oun naa si nii rọ ọba loye.
O ni: "Bẹẹni, mo ṣetan lati gba bi esi idibo naa ba ti ṣe lọ si gẹgẹ bii ifẹ Ọlọrun, mo si ni igbagbọ to jinlẹ ninu ifẹ Ọlọrun."











