NigeriaDecides2019 : Kíni àwọn ohùn tó ṣé kókó tó yẹ ká mọ ṣáájú ìdìbò

Ọjọ a da ti ko ti gbogbo ọmọ Naijiria yoo jade lati dibo yan aarẹ tuntun ti yoo tukọ orileede naa fun ọdun mẹrin.
Jakejado Naijiria ni awọn oludibo ti n jẹ ọrọ idibo yi lẹnu ti ajọ eleto idibo naa ko dawọ iṣe duro nipa eto idibo ohun.
Ẹgbẹ oṣelu mẹtalelaadorin ni yoo dije du ipo Aarẹ ti oludije 1,848 ti 1,615 ninu wọn jẹ okunrin ti obinrin 233 ṣi n du ipo 109 asoju ile asofin agba.
Fun aaye 360 to wa fun ile asojusofin, awọn oludije 4,635 ni wọn du ipo ohun ti a ri ọkunrin 4,066 to n du ipo naa ti obinrin si jẹ 569 to n gbero lati soju awọn eeyan wọn.
Awọn nnkan wọnyi se pataki lati mọ nipa idibo naa, ni eyi ti a fi ṣe atupalẹ ni ṣoki si isalẹ bayi:
Rii wi pe PVC rẹ wa ni tosi
Ko si ani ani pe ẹni to ba ni PVC lọ́wọ lo le kopa ninu idibo ọla ati ọmiran ti o ba waye lasiko ibo gbogboogbo yii.
Bi o ba mọ ibi ti o fi kaadi idibo rẹ si ri wi pe o wa kalẹ ki o si ma ṣeṣi mu kaadi miran dipo rẹ.

Asiko yi kii ṣe igba ti eeyan ma n ya elomiran ni kaadi rẹ,kaadi rẹ ni agbara rẹ, ri wi pe o mojuto daada
Tete kuro nile lọjọ ibo
Gẹgẹ bi ohun gbogbo to ni eto, ajọ INEC fi gbedeke si asiko ti idibo yoo fi waye.
Ti o ba jẹ ẹni ti ko fẹ pẹ pupọ lori ila, yara kuro nile rẹ lasiko ki o ba le dibo lasiko.

Ma ṣe gbagbe pe ijọba ti kede eto irinna laarin aago mẹfa si aago mẹfa irọle.Oun ti eyi tunmọ si ni wi pe ko ni si irina ọkọ laarin igba yi nitori naa tete ṣe eto bi o ti ṣe de aaye idibo rẹ lasiko
Wọn ko fi aye gba lilo ẹrọ alagbeka ninu aye idibo
Awọn ajọ eleto idibo Inec ti n lọgun ọrọ yi ti pe ṣugbọn a ko ni ye fi to arawa leti.
Bi o ba n bọ wa si ibudo idibo, o le mu foonu rẹ lọwọ ṣugbọn to ba ti wọ inu aaye idibo gangan, ko ni si aaye fun ọ lati lo.

Idi ti Inec lawọn lodi si lilo foonu ni ki awọn eeyan ma ba le lo foonu wọn fun ibo rira ati tita.
Ma se wọ aṣọ ẹgbẹ oṣelu tabi ami ẹgbẹ kankan lọ si aye idibo
Gbogbo ipolongo idibo fun ipo Aarẹ ati awọn ile asofin orile-ede Naijiria ti de opin lọjọ kẹrinla, osu keji.
Fun idi eyi ko tọna lati wọ aṣọ ti yoo ma polongo ẹgbẹ kankan.

Fun aabo tara rẹ naa lọwọ awọn to le fẹ dẹyẹsi ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan tabi omiran,o ṣe pataki ki o ma fun wọn laaye pẹlu pe o wọ aṣọ to jẹ ti ẹgbẹ oṣe
lu kankan.
Jẹun tabi ki o ni etokale de inu rẹ
Okun inu laa fi gbe ti ita.
Toun ti bi o ti ṣe wuwa ki ẹ dibo yin bo ti 'ṣe tọ ati bo ti ṣe yẹ,a ko ni fẹ ki ẹ ma lokun lati kopa ninu idibo naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ idibo ko ni si lilobibọ ti pupọ ninu awọn olounjẹ ko si ni patẹ.
Fun idi eyi, ri wi pe o jẹun ki o to kuro nile tabi ki o si ṣeto ounjẹ rẹ lọwọ.
A ki baa mọ,ti o ba ri awọn to gbe ounjẹ jijẹ wa si ibi eto idibo naa,ko si ofin to de wi pe ki a jẹun ti ebi ba n pa wa.Ṣaa ti mu owo lọwọ lati ra ounjẹ naa
Ma di owo pupọ wa si aaye idibo
Aaye idibo kii ṣe ibi ti eeyan n di owo pupọ lọwọ lọ.
Fun idi meji la fẹ ki ẹ sọra pẹlu owo pupọ.
Akọkọ ni pe awọn ole le jin owo naa mọ ẹ lara nibi wọduwọdu idibo.
Ẹkeji ni pe awọn agbofinro ni ẹni to ba di owo to ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira lọwọ wa si ibi idibo yoo salaye ti awọn ba ri iru owo bẹ,oun ti o fẹ fi ṣe.
Abọ ọrọ laa sọfun ọmọlouabi, ẹ ri wi pe ẹ tele ofin idibo ki ẹ si yago fun wahala lọjọ ibo.
















