Nigeria 2019 Elections: Àwọn tí ìdìbò kò dí lọ́wọ́ iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lasiko ti eto idibo ba n waye ni Naijiria, ki i si lilọ bibọ ọkọ lọjọ idibo.
Bakan naa ni gbogbo ileeṣẹ maa n wa ni titi pa, ayafi awọn kan ti iṣẹ wọn ṣe koko, ti aiṣi ilẹkun wọn le ṣe akoba fun araalu.
Ileeṣẹ ọlọpaa: Ileeṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bi ọkan gboogi lara awọn ileeṣẹ eto aabo ni Naijiria ti wọn ko le ṣalaikopa ninu eto idibo Naijiria.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ko awọn oṣiṣẹ rẹ si ibudo idibo kọọkan, ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe ileesẹ ọlọpaa kankan ko ni i jẹ titi pa lasiko eto diibo.
Awọn ọmọ ogun: Awọn ọmọ ileeṣẹ ologun naa ko ni i gbẹyin ninu lilọ bibọ lasiko eto idibo gbogboogbo ọdun 2019.
Iṣẹ wọn si ni lati daabo bo gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria. Ati lati dena awọn janduku to le fẹ da wahala silẹ lasiko ti eto idibo ba n lọ lọwọ.
Oṣiṣẹ eto ilera: Bi gbogbo oṣiṣẹ ko ba ti ẹ le jade lasiko idibo, kii ṣe bi ti awọn eleto ilera, nitori pe iṣẹ irapada ẹmi ṣe koko. Nitori naa ẹnikẹni to ba jẹ oṣiṣẹ eto ilera ni anfaani lati lọ si ibi iṣẹ rẹ ti eto idibo ba n lọ lọwọ, ti ẹnikẹni ko si ni i da a duro.

Oríṣun àwòrán, Media for Medical
Awọn kan lara awọn eleto ilera yii, lati awọn ileewosan, ati ajọ aladani tilẹ maa n lọ kaakiri ibudo idibo lati pese itọju pajawiri fun ẹnikẹni to ba farapa tabi nilo rẹ lasiko eto idibo.
Oṣiṣẹ ina mọna-mọna ati panapana: Awọn oṣiṣẹ to n mojuto ina mọna-mọna, ati awọn oṣiṣẹ pana-pana naa maa n wa nibi iṣẹ wọn lasiko ti idibo ba n lọ lọwọ, nitori ki wsn le mojuto awọn iṣẹlẹ ijamba ina to ba waye.
Awọn akọroyin : Ṣe Yoruba bọ, wọn ni 'eti ọba nile, eti ọba l'oko, eeyan lo n jẹbẹ. Iṣẹ kekere kọ ni awọn ileeṣẹ iroyin n ṣe ṣaaju, lasiko ati lẹyin ti eto idibo ba waye. Awọn akọroyin a si maa lọ kaakiri ibudo idibo lati maa fi bi nkan ṣe n lọ to awọn araalu leti.
Awọn to n ta ounjẹ: Ipa kekere kọ ni awọn to n ta ounjẹ, nkan ipanu loriṣiriṣi, omi ati nkan mimu ẹlẹrin-dodo, nko lasiko eto idibo Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eyi ribẹ nitori pe ọpọlọpọ oludibo ni yoo ti fi ile wọn silẹ lati owurọ kutu lọ si ibudo idibo wọn. Ṣe okun inu lasi fi n gbe titi, eyi ni kii jẹki awọn olounjẹ bi irẹsi, amala, awọn ipanu ti wọn n fi iyẹfun ṣe ati bẹẹbẹ lọ ṣe maa n patẹ si awsn ibudo idibo.
















