2019 Elections: Sowore ní pàṣán ni Buhari yóò fi bá Nàìjíríà ṣe ní sáà kejì

omoyele sowore

Oríṣun àwòrán, Omoyele sowore

Àkọlé àwòrán, Sowore ni omi n bẹ laamu fun idagbasoke eto idibo lorilẹede Naijiria

Oludije fun ipo aarẹ to kọja labẹ oṣelu AAC lorilẹ-ede Naijiria, Ọmọyẹle Ṣoworẹ ti sọ pe oun ko lee pe aarẹ Buhari lati kii ku oriire.

O ni nitori pe ko si idaniloju fun oun pe lootọ ni aarẹ Buhari bori lọna to tọ lasiko idibo naa.

Ṣoworẹ ṣalaye ọrọ yii lasiko to fi n ba BBC News Yoruba sorọ lori ikanni ayelujara facebook.

Ọmọyẹle Ṣoworẹ ni afi bi oun yoo ba pa irọ tan ara oun atawọn to n tẹle oun lẹyin ni oun yoo fi sọ pe lootọ ni Buhari bori lọna to tọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Issa Aremu: ṣàlàyé kíkún nípa èròńgbà ẹgbẹ́ Labour to bá jáde

Oludije ẹgbẹ oṣelu AAC nibi idibo sipo aarẹ naa tun ṣalaye siwaju sii pe ijọba paṣan ni ijọba Buhari ni saa keji rẹ yii yoo jẹ fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Ọmọyẹle Ṣoworẹ ni lara awọn ohun to kọ oun lominu nipa eto idibo sipo aarẹ lorilẹ-ede Naijiria ni iha kokan mi ti awọn oludije kọ si idibo naa.

Àkọlé fídíò, Yinka Ajia: ìbẹ̀rù Ọlọrun ni mo fẹ́ fi tukọ̀ Kwara ti mo ba wọlé

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni iye awọn eeyan to jade fun eto idibo apapọ to kọja lo fẹẹ kere julọ lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada sinu eto iṣejọba tiwantiwa lọdun 2019.

O ni aṣẹ ti aarẹ pa pe ki wọn gbẹmi lẹnu ẹnikẹni to ba ji apoti ibo gbe ati bi awọn ologun ṣe pọ biba lasiko idibo naa kun ara ohun to fa bi awọn eeyan ṣe dẹyẹ si eto idibo naa.

omoyele sowore

Oríṣun àwòrán, omoyele sowore

Àkọlé àwòrán, Ṣòwòrẹ́ tó jẹ́ olùdíje AAC ní ìdí tí òun kò fi leè kí ààrẹ Buhari kú oríire ni pé ọ̀na èrú ló fi wọlé

Oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu AAC naa ni omi ṣi n bẹ lamu fun eto idibo lorilẹ-ede Naijiria.

O ni gbigba kaadi idibo alalopẹ ṣaaju idibo naa ku diẹ kaato ati pe ajọ eleto idibo INEC ko sa ipa to to lati rii pe awọn eeyan gba kaadi naa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.

Nigba ti o wa n sọrọ lori ọna abayọ fun eto idibo to dan mọran lorilẹ-ede Naijiria, Ṣoworẹ ni gbigba ilana idibo igbalode, (electronic voting) laaye yoo ṣe ọpọ anfani fun ilọsiwaju eto idibo ati iṣejọba awarawa lorilẹede Naijiria.

"Ohun to kun fun Naijiria lati ṣe ni ilana idibo igbalode (electronic voting) ki awọn eeyan lee wa ninu ile wọn ki wọn si dibo lai si inira. Inira pọ pupọ ju fun eto idibo o wa mu ki idibo naa maa fa bi igbin."

O ni ara awọn ohun rere to farahan lasiko eto idibo apapọ naa ni omilẹgbẹ awọn ọdọ to jade dije ti wọn si gbiyanju kọja bi awọn eeyan ati onwoye ṣe lero ṣaaju idibo naa lọ.

O rọ aarẹ Buhari lati tete yan awọn minisita ti yoo baa ṣiṣẹ, idagbasoke ọrọ aje, ipese iṣẹ ati ọrọ ajelẹgbẹ oṣelu

Àkọlé fídíò, #NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí