2019 Election: Àwọn oloṣelu tó yege àti àwọn to fidirẹmi

Oríṣun àwòrán, AFP
Ǹnkan tó báni lójiji jùlọ ni tí ìjákulẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn baba ìsàlẹ̀ alágbára ti wọn ń fi owo wọn àti agbára láti yan ẹni to ba wù wọn sípò lásìkò ìdìbò. Awọn míràn tó tún yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ tó wà lórí àléfà sáájú ìdìbò náà tún fìdírẹ̀mi.
Ọ̀pọ̀ àwọn oléṣèlú nla tó fidirẹmi àti àwọn to yege níbi ìdìbò tó wáye lọ́jọ́ kẹtàlélógun osu keji ọdun, 2019
Awọn to fidirẹmi
Bukola Saraki - Ile Igbimọ Aṣofin Àgbà

Dídojú ẹni to jẹ ẹni kẹta ninu ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nínú òṣèlú jẹ ohun to runi nínú púpọ̀. Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta tó jẹ àọàrẹ ile ìgbìmọ̀ aṣofin sùgbọ́n òun tún ni alága ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Peopl's Democractic Party (PDP).
O hàn gbangba-gbàngbà pé ǹkan ò lọ dédé láàrin ààrẹ Muhammadu Buhari àti Bukola Saraki nítori ààrẹ gbé ìwádìí dìde síì nítori ẹsún ìwà ajẹbánu. Sùgbọ́n ilé ẹjọ to ga jùlọ dájọ pé ó yege nínú gbogbo ẹ̀sùn ti wọn fi kàn-án nínú osù keje tó si lọ si inu ẹgbk òṣèlú PDP ní oṣù to tèlé.
O gbìyànju láti pada síle igbimọ asofin agba gẹ́gẹ́ bíi àsoju gbungbun ìpínlẹ̀ Kwara sùgbọ́n olùdíje lábẹ APC.
Dokita Ibrahim Oloriegbẹ yẹ aga mọ nídìí, èyí sì ló fi òpin si ìjẹgaba idile Saraki to tí ń fọba jẹ láti bíì ààdọta ọdún sẹ́yìn.
O hàn gbangba -gbangba pé ìfọba jẹ Saraki ti ṣú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Kwara nítori wọn ń rẹ̀yìn ninu ìdagbasoke àti gbogbo àwọn ohun amuludun, èyí sì ló mú ki àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ ariwo "O TO GẸ'' ti wọn si rẹ́yìn ìjọba rẹ̀.
Godswill Akpabio- Omo ile igbimọ Aṣofin tí ń soju Akwa Ibom North-West

Oríṣun àwòrán, Akpabio
Bábá ìsàlẹ kan náà ni èyí ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ní bi to ti jẹ gomina léèmeji, sùgbọ́n lọtẹ̀ ojúgbà rẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú PDP Chris Ekpenyong ló gbàá mọ lọ́wọ́.
Akpabio ti oun náà jẹ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta kúrò nínu ẹgbk oselu PDP lọ APC sùgbọ́n àwọn èniyan fi ìbò wọn wu nidi lóri oye.
Rabiu Musa Kwankwaso- Baba Isale Ipinlẹ Kano

Sẹnatọ tó wà nile asofin, tó tun jẹ Gomina léèmeji ní ìpinle Kan, Rabiu Musa Kwankwaso kò wá ipo kànkan mọ sùgbọn gbogbo àwọn oloṣelu tó ńṣe baba isalẹ fun pátá lo fìdírẹmi.
Ẹni ọmọ ọdun mejilélọ́gọ́ta kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ si PDP lẹ́yìn ti ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin oun àti ẹni to gba ipo gomìnà lọ́wọ́ rẹ̀ gómìnà Umar Ganduje.
Sheun Sani-Sẹnatọ Aarin Gbungbun Kaduna

Oríṣun àwòrán, Sheu Sanni
Sheu Sanni tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alátakò ìṣèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari náà fìdí rẹmi nínú ìdìbò to kọja. Ẹni ọmọ ọdun mọ́kànléláàdọ́ta yìí le máà ṣe àjoji si àwọn ènìyàn nítori ìhà ti òun àti gomina ipinlẹ Kaduna El-Rufai bótilẹ jẹ́ pé inu ẹgbẹ́ kan náà ni wọn jọ wà.
Awọn to Jawe olubori
Dino Melaye - Sẹnatọ Kogi West

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye
Ṣẹnatọ Dino Melaye tí ẹnu kìí sì lára rẹ̀ bóri ohun gbogbo láti jáwé olúbori, gẹgẹ bii orukọ rẹ Singing Senator, oníruúru ìdojúkọ nínú òṣèlú pẹ̀lú ìjọba.













