#Otogelagos: Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Eko ní àwọn alátakò Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ pe ọlọ́pàá nígbà tọ́rọ̀ gbẹ̀yìn yọ ni

Oríṣun àwòrán, Tinubu/Facebook, Chike Oti/Facebook
Ayalo ọrọ ni #Otogelagos, eyi to ti gbalẹ kan lori ẹrọ ayelujara laarin ọjọ perete bayii.
Iwadii fi han pe ni ipinlẹ Kwara gangan ni adape ọrọ "O to gẹ" ti bẹrẹ to si wọpọ eleyii ti wọn fi n ṣapejuwe igbesẹ ti awọn ara ipinlẹ Kwara gbe lati dibo yọ Sẹnetọ Bukola Saraki kuro gẹgẹ bi aṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa nile aṣofin.
Ẹwẹ, kete ti Ibrahim Oloriegbe yẹ aga nidi Sẹnetọ Saraki ti wọn si gbagbọ pe amulo ọrọ yii wulo gan ninu igbesẹ wọn, ọrọ naa pẹlu afikun orukọ ipinlẹ Eko eyi to di #Otogelagos bẹrẹ si ni gbilẹ sii lori ayelujara Twitter niOkay Eko.
Koda, awọn ipade ati iwọde kan waye ni ilu Eko ti ọpọlọpọ eeyan ti n lọdi rẹ mọ adape ọrọ yii to ti gbẹnu awọn kan ni ipinlẹ Eko.
Fun apẹrẹ, iroyin kan jade laipẹ pe Àwọn ọlọ́pàá dá ìpàdé àwọn alátakò Tinubu dúró l'Eko. Bẹẹ si ni ninu awọn iwe iroyin to gbe e jade, wọn ni ẹgbẹ Orange Movement to ṣe ipade naa ṣe e pẹlu akori "Titu Eko silẹ ninu igbekun Bourdillon" eleyii ni wọn fi n salaye pe o ti togẹ lEko.
Ẹwẹ, nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko Chike Otti, o jẹ ko di mimọ pe awọn to ṣe agbekalẹ ipade naa gan lo jẹbi tori wọn ko fi to ile iṣẹ ọlọpaa leti.
O ni pataki fifi to ọlọpaa leti naa ni ohun to pada ṣẹlẹ nibi ipade ọhun nitori iru ipade bayii ṣeeṣe ki awọn kan fẹ daa ru.
Ọgbẹni Chike ṣalaye lẹkunrẹrẹ wi pe, ẹgbẹ yii ti baba bẹrẹ ipade wọn ki a to gbọ pe idarudapọ n waye nibẹ. Awn gan ni wọn kan si ọlpaa ti a si lọ ran wọn lọwọ.
O ni "kii ṣe ọlọpaa lo da ipade wọn ru, ọlọpaa gan lo lọ ba wọn pẹtu saawọ to n ṣẹlẹ nigba ti a gba ipe latọdọ awọn to gbe ipade kalẹ pe o ti n daru".
Nigba ti akọroyin BBC bere pe ṣe o daju pe ẹgbẹ Orange Movement pẹlu awọn oloṣelu nla to jẹ adari rẹ ko ṣe eto abo kankan, Otti ni bi wọn ba ṣe e, yoo de ọdọ ohun gẹgẹ bi ipo ti oun di mu.
Amọ ṣa akọroyin ni ṣe o le fi aridaju han ninu iwadii awọn ọlọpaa boya igbesẹ ẹgbẹ ni nkankan ṣe pẹlu #Otogelagos, loju ẹsẹ ni alukoro ọlọpaa fesi pe "mo fi tọwọ tọwọ ni ki a da ipe yii duro. Mi o kii n ṣe oloṣelu nitori naa, mi o si lero lati di ọkan"














