Eze Ndigbo Alex Anozie: Irọ́ ni pé àwọn ọlọ́jà gbọ́dọ̀ dìbò fún APC

Bodija

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA

Àkọlé àwòrán, Ìròyìn kan ní ẹgbẹ́ òsèlú APC fipá mú àwọn ọlọ́jà tó wá láti ẹ̀yà Igbo láti ri pé wọ́n dìbò yan gomina lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú APC.

Adari awọn ẹya Igbo to wa ni ipinlẹ Oyo ti sọ wi pe irọ patapata ni pe ẹgbẹ oselu APC fipa mu wọn lati dibo wọn fun ẹgbẹ naa ninu idibo sipo gomina to n bọ.

Iroyin to jade ninu iwe iroyin kan lorilẹede Naijiria fi lede wipe awọn ọlọja to jẹ ẹya Igbo ni Iwo ni wọn ko jẹ ki wọn taja wọn, ti ọpọlọpọ ile itaja wọn si wa ni titi.

Àkọlé fídíò, Àwọn obìnrin Eko ní àwọ́n kò ṣàṣedànù lórí Sai baba

Iroyin naa fi lede wi pe obinrin ọlọja ti ko fẹ ki wọn darukọ rẹ lo ni wọn fun wọn ni gbẹndeke pe ẹni ti ko ba dibo fun oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC, wọn ko ni si ile itaja rẹ.

Ibadan

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Eze Ndigbo Alex Anozie to jẹ adari awọn Igbo naa lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni irọ ni ẹsun naa, ati wi pe ohun yoo gb si ti iru isẹlẹ bẹẹ ba waye.

Àkọlé fídíò, 'Mi ò ní Bàbá ìsàlẹ̀ ṣùgbọ́n mo ní Bàbá òkè' - Adedoyin

O fikun wi pe ohun tun ti beere daradara lọwọ awọn adari to wa ni ilu Ibadan, ti wọn si sọ wi pe ko si ohun to jọ bii isẹlẹ naa.

Gbogbo igbiyanju lati kan si ile isẹ ọlọpaa lati fi idi ọrọ naa mulẹ ni o jasi pabo.