Ṣẹ rántí pásítọ̀ South Afrika tó ní òun jí òkú díde? Àwọn agbókùú fẹ́ fàá lọ ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Alph Lukau/Facebook
Ẹgbẹ awọn agbokujo ni South Afrika ti ni awọn yoo gbe pasitọ to ni oun ji oku arakunrin kan dide lọ ile ẹjọ́.
Fidio kan ṣe afihan pasitọ Alph Lukau, nibi to ti n pariwo sinu poosi kan to si n sọ fun arakunrin kan ti oku rẹ wa ninu rẹ pe ko ji dide, bi awọn ara ijọ ṣe n patẹwọ.
Ohun ti pasitọ se yii, to waye lẹba ile ijọsin rẹ ti ko jinna silu Johannesburg, ni ọpọlọpọ ti bẹnu atẹ lu bi fidio naa ṣe tan kakakiri.
Awọn eeyan kan ni ọna lati gba owo lọwọ awọn ara ilu ni igbesẹ yii, kii se ootọ rara.
Ileeṣẹ agbokujo mẹta ti kede faraye pe igbesẹ pasitọ naa ba orukọ awọn jẹ, nitori naa, awọn n lọ ile ẹjọ.
Ileesẹ agbokujo Kingdom Blue, Kings & Queens Funeral Services ati Black Phoenix sọ fun awọn akọroyin wipe, awọn oṣiṣẹ ile ijọsin naa tan awọn jẹ.
Wọn ni awon kan ti wọn pe ara wọn ni awọn idile "oloogbe", wa si ọdọ awọn ile agbokujo naa wipe awọn fẹ fun wọn niṣẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Ṣugbọn awọn iwe iroyin ni arakunrin ti wọn pe ni oloogbe naa ko ku.
Ọrọ naa si tun ti mu ki ẹnu tubọ maa kun awọn ayederu pasitọ ni South Afrika.













