Election Update 2019: Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Kwara yóò kọ́ àwọn ìpínlẹ̀ yókù lọ́gbọ́n

Oríṣun àwòrán, @Ogundamisi
Onwoye nipa awọn ohun to n lọ lawujọ wa, to fi ilẹ Gẹẹsi se ibujoko, Kayọde Ogundamisi, ti woye pe oniruuru ẹkọ ni eto idibo aarẹ ati tawọn asofin apapọ to kọja kọ wa.
Ogundamisi, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin ti ajọ eleto idibo kede esi ibo aarẹ ati ẹni to jawe olubori, salaye pe, ọpọ oloselu lo ti kẹkọ bayii pe ọrọ araalu lo se pataki ju ohun ti wọn yoo jẹ lọ.
Nigba to n mẹnuba ihuwasi awọn asofin agba ilẹ wa ni saa eto isejọba taa wa yii, Ogundamisi mẹnuba olori ile asofin agba, Bukọla Saraki pe, yoo fi abajade esi idibo to kọja kẹkọ pe ilu nikan lo dara lati sin ju ara ẹni lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa lo ni, isẹlẹ to waye nipinlẹ Kwara yoo jẹ ẹkọ fun awọn ipinlẹ yoku, ti adari wọn ko ba ro tawọn mẹkunnu mọ eto isejọba wọn, pẹlu afikun pe, inu oun dun pe Bukọla Saraki ko ni pada sile asofin agba mọ ni saa isejọba to n bọ.
Ogundamiloju wa kesi aarẹ Muhammadu Buhari lati maa ba awọn araalu sọrọ loorekoore ko lee mọ awọn ohun ti awọn eeyan n fẹ.
Lori ifilọlẹ saa isejọba to n bọ, onwoye nipa ohun to n lọ lawujọ naa ni Buhari yẹ ko yọ awọn oloye rẹ ti ko ba sisẹ bo se yẹ nipo, ko si fi awọn eeyan to da loju pe wọn yoo sisẹ kara sipo.
Ogundamisi tun ni isẹ ti isejọba Buhari se laarin ọdun mẹrin pọ pups, amọ iroyin ati ipolongo nipa awọn akanse isẹ naa mẹyẹ pupọ.









