Election Update 2019: Kíni ifidirẹmi Saraki tumọ fún òṣèlú Kwara

Oríṣun àwòrán, Facebook/@bukola.saraki/@gbemisola.saraki
Igba kan o lọ bi orere lawọn agba maa n wi.
Lẹyin ọdun mẹjọ ni ipo Gomina ati ọdun mẹjọ gẹgẹ bi asofin agba, Bukola Saraki yoo bẹrẹ igbe aye tuntun gẹgẹ bi ẹni ti ko di ipo ijọba kankan mu.
Ko tii si esi kankan to jade lọdọ gbajugbaja oloṣelu yii lati igba ti o ti fidirẹmi ninu ibo si ipo asoju ile asofin agba fun aarin-gbungbun Kwara titi di bi a ṣe n sọrọ yii.
Ki a to gbọ nnkankan lẹnu rẹ, la ni ki a wo bi ifidirẹmi rẹ yoo ṣe nipa lara oṣelu ipinlẹ Kwara ati ti orile-ede Naijiria lapapọ.
Kwara ti padanu ipo ẹnikẹta to lagbara loṣelu Naijiria
Ni kété ti ariwo idunnu awọn ololufẹ Ibrahim Oloriegbe ba pari ti oju si la, ni gbogbo Kwara yoo pada si okodoro ohun to ba aṣeyọri yi wa.
Eyi si ni pe wọn ko ni ni ọmọ Ilorin nipo igbakẹta ijọba.

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmaad
Ipo Aarẹ ile asofin kii ṣe eleyi ti asofin to ba ṣẹṣẹ wole si ile asofin maa n jẹ.
Ki Saraki naa to de ipo ọhun, o ti lo saa kan gẹgẹ bi asofin ti o si lo ipo rẹ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn Gomina lati ri atilẹyin awọn Sẹnẹtọ akẹgbẹ rẹ gba.
Ibo gomina to n bọ lọna -iṣẹ nla ni yoo jẹ fun PDP
Ẹgbẹ oṣelu PDP yoo ni lati mura daada ti wọn ba fẹ ṣaṣeyọri ninu ibo gomina to m bọ.
Iku to n pa ojugba ẹni lọrọ to wa nilẹ yi, owe lo n pa fun ẹgbẹ naa ati oludije wọn ninu ibo gomina.

Oríṣun àwòrán, Facebook/atunwaone/@RealAARahman
Pẹlu bi nnkan ti ṣe ri ninu esi ibo aarẹ eleyi ti aarẹ Buhari tipegede nipinlẹ naa, o ṣeesẹ ki awọn eeyan tẹsiwaju lati pari iṣẹ fun APC ninu ibo to ṣẹku.
Saraki kan lọ,Saraki mii n bọ?
Nigba ti Gbemi Saraki aburo Bukọla Saraki fi ile asofin kalẹ ti o gbiyanju ati dije dupo gomina, ifidirẹmi lo gbẹyin rẹ.
Lati igba naa lo ti jọ bi ẹni pe ko fi taratara da si ọrọ oṣelu ipinlẹ Kwara.

Oríṣun àwòrán, Facebook/gbemisola.saraki
Lẹnu ọjọ mẹta yi, o ti n ko ipa ribiribi ninu oṣelu paapa labẹ asia APC ti o si wa lara awọn to lewaju lati gba alejo aarẹ ati igbakeji rẹ nigba ti wọn ṣabẹwo si Kwara.
Ibeere ti yoo ma wa si ọkan bayi ni wi pe, ṣe Gbemi Saraki ni Saraki ti awọn eeyan Ilorin ati Kwara lapapọ yoo maa wo gẹgẹ bi adari ''aafin iṣejọba idile Saraki'' bayii?















