Buhari fi ọ̀kadà, ọkọ̀ àti $500,000 ta orílẹ̀èdè Guinea Bissau l'ọ́rẹ fún ètò ìdìbò wọ̀n

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, MBuhari/Twitter

Aarẹ orilẹede Naijiria, Mohammadu Buhari ti fi ọwọ si pe ki wọn o ko ọtalelọọdunrun din mẹwa irinṣẹ idibo, ọkada mẹwaa, to fi mọ ọkọ Hilux maarun ati ọkọ akẹru meji fun orilẹede Guinea-Bissau.

Bakan naa lo fun orilẹede naa ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Dọla lati fi ran an lọwọ fun eto idibo to fẹ ẹ ṣe.

Aarẹ Buhari paṣẹ fun Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama lati tete jẹ iṣẹ naa fun orilẹede ọhun nitori ipe iranlọwọ pajawiri ti oun gba lati ọdọ ijọba wọn.

Buhari to jẹ Alaga awọn olori orilẹede to wa ninu ajọ ECOWAS buwọlu pe ki minisita naa rinrinajo naa pẹlu Aarẹ ECOWAS, Jean-Claude Brou, lati ṣoju oun l'orilẹede Guinea.

Gẹgẹ bi aarẹ ṣe sọ, igbesẹ naa ṣe pataki lati ri i daju pe eto idibo to fẹ ẹ waye ni Guinea Bissau yoo mu nkan pada bọ sipo l'orilẹede naa.