NYSC: Ọ̀gágun S. Ibrahim di ọ̀gá àgbà àjọ NYSC

NYSC

Oríṣun àwòrán, NYSC

Àkọlé àwòrán, NYSC

Ile iṣẹ ologun orilede Naijiria ti yan Ọgagun S. Ibrahim lati ile iwe giga fasiti ti awọn ologun to wa ni Biu gẹgẹ bi ọga agba tuntun ti ajọ to n ri si agunbanirọ ni Naijiria, NYSC.

Eyi jade ninu atẹjade to sọ nipa iyansipo naa ti Ọgagun agbnusọ ile iṣẹ ologun, Sagir Musa fọwọ si pe yoo gba eku ida lọwọ Ọgagun S.Z. Kazaure.

Àkọlé fídíò, Africa Drum Festival 2019: Eruku sọ níbi àjọ̀dún ìlù l'Abẹokuta

Musa sọ wi pe Ọgagun S. Ibrahim ni Giwa fasiti awn ologun to wa ni Biu, o si ni iyansipo naa paṣẹ ki iṣẹ bẹrẹ ni kia kia.

Àwọn mii ti wọn tun yan sipo ni Ọgagun A.A Goni lati di adari ẹka ologun ni olu ile iṣẹ to n ri si ọrọ to kan ologun kan araalu gẹgẹ bi adari ẹka iroyin.

Bakan naa, Ọgagun F.C. Onyeari lati olu ile iṣẹ awọn ologun lati lọ se adele adari ẹka ounjẹ.