African Drum Festival 2019: Orílẹ̀èdè 23 ló kópa níbi àjọ̀dún ìlù ọdún 2019
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ni aye atijọ, awọn ìlú nilẹ Yoruba ati kaakiri ilẹ Afrika maa n lo ìlù lati ba ara wọn sọrọ. Ìró ilu maa n jẹ ọna ibaraẹnisọrọ laarin eniyan meji tabi ju bẹẹ lọ, bi ẹrọ ibaraẹnisọrọ ṣe ri l'ode oni.
Oriṣiriṣi ọrọ aṣiri si ni awọn eniyan maa n lo ilu lati sọ, ẹni to ba si ni eti ilu nikan ni ọrọ naa le ye.
Ajọdun ilu nilẹ Afrika to maa n waye ni ipinlẹ Ogun l'orilẹede Naijria jẹ afihan ati ṣiṣe ajọyọ ipa ti ilu n ko nilẹ Afrika.

Oríṣun àwòrán, African Drum Ferstival/Facebook
Ọdun 2016 ni gomina ipinlẹ naa, Ibikunle Amosun fi ajọdun naa le lẹ. Ẹlẹẹkẹrin si ni ti ọdun 2019 to n waye nilu Abẹokuta, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun.
Ninu ọrọ to sọ ṣaaju ki ajọdun ọlọjọ mẹta naa to bẹrẹ l'ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, Gomina Amosun sọ pe yatọ si ipinlẹ mẹrindinlọgbọn ni Naijiria ti yoo kopa nibi ajọdun naa l'ọdun yii, orilẹede ilẹ Afrika mọkanlelogun, to fi mọ orilẹede UK ati China ni yoo kopa.

Yatọ si awọn onílù to maa n kopa, awọn akọrin, awọn arinrinajo afẹ ati awọn to fẹran aṣa naa kii gbẹhin nibi ajọdun naa.

Bakan naa ni afihan ijo ati aṣọ oriṣiriṣi ẹya kaakiri Naijiria maa n waye.
Ko yọ ọmọde silẹ, ko si yọ agba silẹ gẹgẹ bi akọroyin BBC ṣe ṣe alabapade awọn ọdọmọbinrin ibeji kan to jẹ ọmọ ọdun mọkanla ti wn si ti n lu ilu lati ọdun mẹta.

Oríṣun àwòrán, AFrican Drum Festival













