2019 Election update: Buhari borí; ó di ààrẹ Nàìjíríà tuntun

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Buhari/Twitter

Àkọlé àwòrán, Buhari wọle leẹkeji

Aarẹ Muhammadu Buhari lo jawe olubori ninu ibo aarẹ orilẹede Naijiria to waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtalelogun, ọdun 2019.

Ajọ eleto idibo INEC lo kede pe aarẹ pe Buhari to dije dupo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC fẹyin Atiku Abubakar to dije fẹgbẹ osẹlu alatako PDP gba lẹ ninu idibo ọhun.

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán, Buhari wọle leẹkeji

Pẹlu esi idibo yii tumọ si pe aarẹ Buhari ni yoo tukọ orilẹede Naijiria fun ọdun mẹrin miran.

Ẹwẹ, ẹgbẹ alako PDP ti sọ pe awọn ko ni gba esi idibo ti ajọ INEC kede lati igba ti wọn ti n ka esi ibo naa.

Buahari jawe olubori ni awọn ipinlẹ bi Kano, Katsina, Bauchi, Kaduna, Bornu, Yobe pẹlu ibo to pọ yanturu.

Muhammadu BUhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán, Buhari fẹyin Atiku gba lẹ

Aarẹ Buhari tun la Atiku mọ lẹ nipinlẹ Osun, Ekiti, Kwara, Kogi ati awọn ipinlẹ miran.

Bakan naa ni Atiku la Buhari fẹyin Buhari gbo lẹ lawọn ipinlẹ bi Adamawa, Benue, Cross River, Abia ati olu ilu Naijiria Abuja