Election Update 2019: Saraki sọ ìdí tó fi fìdírẹmi nínú ìdìbò àpapọ̀

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Saraki

Àkọlé àwòrán, Saraki ní yoo ohun tó ṣẹlẹ̀ yóò fun awọn eeyan lanfani ati ṣe àfiwé àwọn igun òṣèlú mejeeji

Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki ti ṣalaye awọn idi ti oun atawọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara fi fidirẹmi, ninu eto idibo apapọ to waye ni ọjọ Satide.

Saraki sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita, to fi ki awọn to gbe'gba oroke nibi eto idibo naa ku oriire.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Saraki ni, bi o tilẹ jẹ wi pe alaafia jọba lasiko idibo naa, sibẹ aikun oju oṣuwọn awọn ẹrọ ayẹkaadi idibo wo, titẹka kọja iye ibo to yẹ atawọn iwa aitọ miran kaakiri awọn ibudo idibo ni ipinlẹ naa, kun ohun to faa ijakulẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara.

Dokita Saraki ni, oun ki gbogbo awọn ti INEC kede gẹgẹ bii olubori ku oriire ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu oun yoo gbe igbesẹ to ba tọ, nigba to ba ya lori awọn kudiẹkudiẹ naa.

Àkọlé fídíò, Election Update 2019: Lẹ́yìn lílọ Saraki, Kwara yóò ṣún síwájú ni

"Gẹgẹ bii ẹni to wa lati inu ẹbi ati eto oṣelu to gbilẹ lati ibẹrẹ pẹpẹ ninu iṣiṣẹ sin araalu ati idagbasoke awọn eniyan rẹ, ireti mi ni pe awọn eeyan wa yoo maa ri ere pipe ni igba gbogbo.

Ohun to ṣẹlẹ yii yoo tilẹ tun fun awọn eeyan lanfani ati gbe ẹgbẹ mejeeji si ẹgbẹ ara wọn fun ayẹwo ati afiwe. Ju gbogbo rẹ lọ awọn to bori ni idibo satide kii ṣe ọta mi. ọmọ ipinlẹ Kwara kan naa bii temi ni wọn jẹ."

Ibrahim Oloriẹgbẹ lo gbẹyẹ mọ Saraki lọwọ ninu idije fun ijoko aṣofin agba, fun ẹkun idibo guusu ipinlẹ Kwara.