Election Update 2019: Sowore dẹ́bi aijáde dibo àwọn èèyàn rú ìhàlẹ̀ Buhari

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Oludije ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, AAC, Omoyele Sowore ti fesi si ijawe olubori Aarẹ Muhammadu Buhari ninu idibo aarẹ Naijiria.
Soworẹ ni ki awọn ọmọ Naijiria ma gbaradi nitori ijọba pasan ni wọn dibo fun ti gbogbo wọn yoo si ni ipin ninu rẹ.
Soworẹ salaye ọrọ yi wa nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori akanṣe eto nipa idibo aarẹ Naijiria.
''Ibo yi ko bojumu.Ti ẹ ba wo daada, ẹ o ri wi pe awọn eeyan ko tuyaya jade paapa julọ nilu Eko lati dọwọ idunnu esi ibo''
Sowore tẹsiwaju pe, pupo eeyan ni ko ri bi dibo latari kọnukọhọ to wa ninu eto idibo naa.
O si da ẹbi aijade dibo daada awọn ara ilu ru ọrọ ihalẹ ti aarẹ Buhari sọ saaju idibo.
Iṣoro ko ni si fun ọdọ mọ lọjọ iwaju
Sowore dupe lọwọ awọn ọmọ Naijiria to gbaruku ti ẹgbẹ rẹ ti wọn fi ṣe ipo kẹta ninu ibo naa.
O ni bayi ti awọn ti ri ipa ti awọn oludije ọdo ko,iṣoro ko ni si lọjọ iwaaju fun awọn ọdọ lati de ipo oṣelu.
''Asiko ọ̀dọ́ ni ọdun mẹrin to n bọ lọna.''
Sowore wa pe fun atunto eto oṣelu ki o ba le jẹ ki awọn ọmọ Naijiria laanfaani lati kopa daada.
Nigba ti atọkun eto beere lọwọ rẹ pe, ki ni yoo ṣe, to ba jẹ oun lo wole gẹgẹ bi Buhari? Sowore ni kiakia lohun yoo yan awọn ti yoo ṣe ijọba ti awọn ko si ni dawọ iṣejọba duro.
''O ti wa lori oye tẹlẹ, ko si yẹ ki idiwọ kankan waye lati maa tẹsiwaju pẹlu iṣejọba. Ọsẹ kan pere ni mo ma fikede Minisita tuntun, ka ni emi ni Buhari."












