Election Update 2019: Atiku tí ṣàlàyé ìdí tí kò fí kí Buhari kú oríire

Oríṣun àwòrán, @atiku
Oludije ipo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubaka,r to ṣe ipo keji ninu idibo aarẹ Naijiria ti fesi si ibo Naijiria ti Muhammadu Buhari ti pegede.
Ninu ọrọ to fi sọwọ sawọn akọroyin ati loju opo Twitter rẹ, Atiku ni oun ko ni gba ki wọn fun okun mọ ọrun ijọba awa ara wa lorileede Naijiria.
Atiku ni lati ọgbọn ọdun ti oun ti n ja ija ijọba tiwantiwa, oun ko ti ri ibi ti wọn ti tẹju iṣejọba awa ara wa loju mọlẹ bi ti idibo ọjọ kẹtalelogun osu Keji to waye ni Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba paṣan ní Nàìjíríà dibo fún, yóò kàn gbogbo wà-Sowore
- Atiku: Màá foríji àwọn tó kówó ìlú jẹ́ tí mo bá di àárẹ
- A kò ní fárí apá kan, dá apá kàn sí nínú ìjọba wà - Buhari
- Ẹ wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká sẹ́nẹ́tọ̀ tó kùnà nínú ìdìbò ilé aṣòfin
- Buhari la Atiku mọ́lẹ̀, o di ààrẹ Nàìjíríà tuntun
- Ìdí tí mo fí kọ̀ èsì ìbò ààrẹ - Atiku ṣàlàyé
- Ìjọba paṣan ní Nàìjíríà dibo fún, yóò kàn gbogbo wà - Sowore
O sọ pe l'ọdun 2017 ''Aarẹ Yar Adua ti ẹ kabamọ idibo to gbe wọlẹ, amọ o ṣeni laanu pe, awọn to doju ijọba arawa bole lọdun 2019 n ga apa ni''
''Fun idi eyi, mọ tako esi ibo ọjọ kẹtalelogun to waye ni Naijiria, maa si gbe ọrọ na lọ si ile ẹjọ''
Atiku Abubakar tẹsiwaju pe, oun ko ba ti pe ẹni to jawe olubori lati ki ku oriire, kani oun fidirẹmi lọna to tọ ati to yẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
PDP ní èsì ti wọn kéde kìí ṣe ojúlowo ìbò ti Nàìjíríà dì
Ẹgbẹ́ alátakò People's Democratic Party (PDP) ní àwọn yóò ṣe gbogbo ǹkan to wà ní ìkápá àwọn, tó fi mọ ìlànà òfin láti fi ẹ̀hónú àwọn hàn ló ri ìjáwé olúbori ààrẹ Muhammadu Buhari nínú ìdìbò ọdún 2019.
Ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún tó kọ̀ láti fọ́wọ́ sí ìwé èsì ìbò tí àjọ elétò ìdìbò fi kédé pé Buhari ló jáwé olúbori, tun sọ pe o ní kọ́nukọ́họ ninu.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Lẹ́yìn ti INEC kédé pé, Buhari ló fi ìdí Atiku rẹmi nínu idibo náà ní alága àjọ INEC ọjọgban Yakubu Mahmood sàláyé pé ìyàtọ̀ tówà láàrin àwọn oludije méèjèjì pọ ju àwọn ìbò ti wọn dànù lọ nítori náà kò ní ipa kànkan lóri èsì ìdìbò.
Gẹ́gẹ́ bí Yakubu ṣe sọ, gbogbo àríwísí àti àkíyesi ti PDP ṣe ni àwọn yóò múlò ní ọjọ iwájú tó fi mọ ìdìbò ọdun 2023.
Lásikò tó ń fesi láàrò Ọ́jọrú, lóri àbájáde ikede ìdìbo Buhari, okan ninu asojú ẹgbẹ PDP, Osita Chidoka sọ fun àwọn akọroyin nílu Abuja pé, àwọn èsì ti wọn kéde kìí ṣe ojúlowo ìbò ti àwọn ènìyàn Nàìjíríà dì.













