Ìdí rèé tí Uber fi kógbá wọlé ní Naijiria lẹ́yìn ọdún méjìlá tó fi ṣe okòwò ọkọ̀ èrò

Ọkọ Uber dudu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ Uber to n ṣokowo ọkọ ero ti kede wi pe awọn ti kogba wọle lorilẹede Naijiria lẹyin ọdun mejila ti wọn ti n ṣiṣẹ ni Naijiria.

Uber ṣalaye wi pe igbesẹ to nira lo jẹ fawọn lati kuro ni Naijiria, amọ, nnkan ti okowo awọn n fẹ ni awọn ṣe.

Ṣaaju ni oriṣiiriṣii iroyin ti gba ori ayelujara kan wi pe Uber ti kogba wọle ni Naijiria.

"Naijiria ati Uganda nikan la ti kogba wọle, a si n ṣiṣẹ lawọn orilẹede mii nilẹ Afirika"

Eyi lo jẹ ki BBC kan si ileeṣẹ naa ti wọn si fi idi rẹ mulẹ wi pe lootọ lawọn ti kogba wọle ni Naijiria.

Ileeṣẹ naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ wi pe lorilẹede Naijiria ati Uganda nikan lawọn ti kogba wọle, wọn ni awọn ṣi n ṣiṣẹ lawọn orilẹede mii nilẹ Afirika.

Ileeṣẹ naa ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lỌjọru ọjọ keji oṣu Kẹsan an wi pe ''Uber pinnu lati kogba wọle ni Naijiria ati Uganda tori nnkan ti okowo wa n beere fun ni nilẹ Afirika ni igbesẹ ti a gbe yii.''

Ọpọ onibaara Uber ni wọn ti fi atẹjiṣẹ ransẹ si wi pe awọn ti tilẹkun ileeṣẹ awọn lorilẹede Naijiria.

Ileeṣẹ naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe aapu tawọn onibaara maa n dari ibeere wọn si yoo si maa ṣiṣẹ titi ti ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹsan an yii lati maa dahun gbogbo ibeere awọn eeyan.

''A si wa nilẹ Afirika, a n wo o bi okowo wa yoo ṣe maa dagba si i.

A maa gbajumọ awọn ibi ti okowo wa ti maa ni ere to dara fawọn awakọ wa bayii.''

Lọdun 2014 ni ileeṣẹ Uber de si orilẹede Naijiria, ileeṣẹ naa si gbooro ko to di Ọjọru ti wọn kede pe awọn ti kogba wọle.

Idi ree ti Uber fi kogba wọle ni Naijiria

Ileeṣẹ Uber ṣalaye wi pe lorilẹede Naijiria ati Uganda nikan lawọn ti kogba wọle nilẹ Afirika.

Ileeṣẹ naa sọ pe awọn ṣi wa kaakiri awọn orilẹede mii nilẹ Afirika.

Uber ṣalaye wi pe nnkan ti okowo awọn n beere fun ni igbesẹ tawọn gbe lati kogba wọle ni Naijiria lẹyin ọdun mejila.

''Lẹyin ti a ṣe agbeyẹwo okowo wa daadaa ni a pinnu lati kuro ni orilẹede Naijiria ati Uganda.

A fẹ gbajumọ okowo lawọn ibi ti a ti le ri ere to dara fun ileeṣẹ wa ati fawọn awakọ wa bakan naa.''

Ileeṣẹ naa ko ṣai ṣalaye wi pe bawọn ṣe kuro ni Naijiria ko ni ohunkohun ṣe pẹlu aṣẹ ti ajo FAAN to n ṣakoso papakọ ofurufu ni Naijiria pa fawọn to n ṣe okwo ọkọ to n gbero lawọn papakọ ofurufu Naijiria.

Ki ni yoo ṣẹlẹ sawọn awakọ atawọn onibaara Uber ni Naijiria bayii?

Ileeṣẹ Uber ni awọn oṣiṣẹ ni Naijiria ti wọn n bawọn dokowo papọ.

Uber sọ pe awọn si n bawọn oṣiṣẹ awọn to fi mawọn awakọ awọn sọrọ lori igbesẹ yii.

Wọn ni awọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣe atilẹyin fawọn oṣiṣẹ ti igbesẹ yii yoo ṣakoba fun iṣẹ wọn.