Wọ́n rí alààyè obìnrin tó ti kú tẹ́lẹ̀ nínú mọ́ṣúárì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obinrin kan ti n gbadun diẹ̀-diẹ̀ nile ìwosan lẹ̀yin ti wọn ba laaye ninu firiiji ti wọn n ko oku pamọ si ni mọṣuari.
Obinrin naa ni wọn gbe lọ si ile igboku-pamọ-si to wa ni Carletonville, ni ẹkùn Gauteng, l'orile-ede South Africa lẹyin ti awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi sọ pe o ti ku ninu ijamba ọkọ to waye.
Ṣugbọn, ori ko o yọ nigba ti oṣiṣẹ mọṣuari kan pada lọ yẹ ẹ wo nibi ti wọn gbe e si.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ sọ fun BBC pe obinrin naa ti wọn ko darukọ ti n gba itọju ni ile Iwosan kan to wa ni ilu Johannesburg, lẹyin ti awọn onimọ nipa ẹya ara fi ti ọwọ si i.
Bakan naa ni iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ naa, ti awọn ẹbi rẹ si n fẹ mọ ohun to faa ti wọn fi kọkọ kede oku rẹ.
Ọkan lara awọn ẹbi obinrin naa, to fi orukọ bo ara rẹ laṣiri sọ fun BBC pe,''gẹgẹ bi ẹbi, a o ni ohunkohun lati sọ, ayaafi ti gbogbo awọn ọlọpaa, ati oṣiṣẹ adoola ẹmi, to fi mọ awọn oṣiṣẹ mọṣuari ba wa nijoko o.
A n fẹ idahun.

Bakan naa ni arakunrin naa sọ pe ohun to janilaya ni iṣẹlẹ naa.
Ṣugbọn, olori fun ileeṣẹ adoola ẹmi, Gerrit Branick, ni ko si ẹri kankan to fi idi rẹ mulẹ pe ẹ̀bi awọn oṣiṣẹ awọn ni, nitori gbogbo wọn lo mọṣẹ.
Igba akọkọ kọ niyi ti iru iṣẹlẹ bẹẹ yoo waye ni South Africa. Ọkan ti waye bẹ ri ni 2011, nigba ti ọkunrin aadọta ọdun kan ji ninu mọṣuari kan to wa ni Cape Town, to si bẹrẹ si ni pariwo.
Bakan ni omiran ṣẹlẹ si ẹnikan to ni ijamba ọkọ, ti wọn si sọ pe o ti ku, ko to di pe wọn rii to n mi l'ọjọ keji.
Ṣugbọn o pada ku lẹyin wakati marun un lẹyin ti wọn ri.















