Plateau Crisis: Àafa f'àwọn Krìstìẹ́nì pamọ́ sínú mọ́ṣáláṣí

Nígba tí aafa alaanu yii rii tí ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ń sá wọ abúle rẹ̀ ní Nghar Yelwa ní Ìpínlẹ̀ Plateau l'ọjọ́ Aikú, kò ròó lẹ́ẹ̀méjì to fi ṣílẹ̀kùn láti gbà wọ́n wọlé.
Àwọn tó ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn náà wá láti abúlé kan ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Barkin Ladi níbi tí àwọn darandaran agbébọn wọ̀ láti pa àwọn ènìyàn.
Lẹ́yìn ò rẹyìn, ènìyàn mẹ́rìndínláàdọ́rin ni àwọn ọlọ́pàá ní ó kú, ṣùgbọ́n àwọn ará ìlú ní wọ́n ju igba lọ.
Ali sọ fún BBC pe, "Mo kọ́kọ́ mú àwọn obìnrin wọ ilée mi láti fi wọ́n pamọ́. Lẹ́yìn náà ni mo wá mú àwọn ọkùnrin wọ inú mọ́ṣáláṣí láti fi wọ́n pamọ́." Ó lé ní'gba ènìyàn tí ààfá náà dóólà ẹ̀mí wọn.
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn Berom àti àwọn Mùsùlùmí to sá kúrò níbi ìkọlù náà ló sá lọ sà wọ Abule Nghar Yelwa fún ààbò.

Èyí tó ba ni lérù ju ni pé, àwọn agbébọn náà lọ bá Imam Ali, wọn ní kó fa àwọn Krìstìẹ́nì tọ wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n pa wọ́n ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé Mùsùlùmí ni gbogbo àwọn tó wà lọ́dọ̀ òun.
Bẹ́ẹ̀ ló ṣe parọ́ tó fi bẹ àwọn agbébọn náà láti máa lọ.
Bẹ́ẹ̀ ni orí ṣe yọ àwọn Berom to wà ni abúlé ọhun. Ṣùgbọ́n bí wọn kò ṣe nilé báyìí, mọ́ṣáláṣí náà ni ibi tí wọ́n ń gbé.
BBC gbọ́ pé ọdun mélòó kan sẹ́yìn tí àwọn Mùsùlùmí ìlú náà ń wá ilẹ̀ láti kọ́ mọ́ṣáláṣí sí, àwọn Berom ló fún wón nílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́.













