Ìkọlù Plateau: Ẹyìn aṣáájú ìlú gbọdọ mojuto àlàfíà

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Ààrẹ Mùhámádù Buhari ti orílẹ̀èdè Naijirià ti ke si àwọn olórí ìlú nipinle Plateau láti mú ibasepọ àlàfíà láàrin àwọn èèyàn wọn n'isẹ.
Aarẹ Buhari parowa yìí nigba to n ṣe ìpàdé pẹlú awọn alenuloro ni ìpínlè náà lọjo ìṣẹgun.
Buhari ni ipaniyan to gbérí padà ní Plateau jẹ́ òun tó n kọni lominu ati pé ìjọba òun yóò wá wọ̀rọ̀kọ̀ fí ṣada láti dẹkùn rẹ
Ọpọ èèyàn ló ti pàdánù ẹmí wọn nínú ikọlù láàrin àgbẹ àti darandaran.
Ìṣẹlẹ yìí sí ti mu kí ọpọ bẹnu àtẹ lú ètò ààbò lorílẹ̀-èdè eleyii ti wọn ní ko gbámúsé.
Ṣáájú ní igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo ti ṣe àbẹwò sí ìpínlè náà.








