CAN, àwọn ajàfẹ́tọ̀ pè fún ìdájọ́ lórí ìpànìyàn Plateau

Awọn obinrin kan n sunkun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, CAN ni ikọlu ọhun ṣe afihan ijakulẹ to n waye lori ọrọ abo lorilẹede Naijiria

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria, CAN pẹlu ajọ fun idaabo bo ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria, NHRC ti pe fun fifi awọn to wa nidi iṣẹlẹ ipaniyan to waye nipinlẹ Plateau jofin.

Gẹgẹ bii ọlọpaa ṣe sọ, eeyan mẹrindinlaadọrun lo ku ninu ikọlu naa to waye ni Barkin Ladi nipinlẹ Plateau.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn aṣiwaju ẹgbẹ darandaran lorilẹede Naijiria, Miyetti Allah, ti sọ pe ikọlu ẹsan ni ikọlu naa, ẹgbẹ CAN ti ke si ijọba lati tete wa ọna fi mu awọn to wa nidi ikọlu naa.

CAN ni ikọlu ọhun ṣe afihan ijakulẹ to n waye lori ọrọ abo lorilẹede Naijiria.

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ijọba àpapọ̀ ní ìgbésẹ̀ àwọn agbófinró ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣàwárí gbogbo àwọn tó wà nídí ìkọlù náà

" A mọ pe awọn ileto ti ọrọ kan ko tii lee sọ ni pato iye awọn eeyan wọn ti wọn pa, ṣugbọn ibanujẹ nla lo jẹ wi pe eeyan mẹrindinlaadọrun lo ku ninu ikọlu ọhun gẹgẹ bii awọn ọlọpaa ṣe sọ titi kan awọn obinrin ati ọmọde."

Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni ko si iwulo fun iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ awọn ajọ alaabo gbogbo bi o ba lee ṣeeṣe fun awọn amokunṣika lati pa ọpọlọpọ eeyan lawọn ileto laisi si pe awọn ileeṣẹ alaabo n doola wọn.

Bakan naa ni akọwe ajọ fun idaabo bo ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria, NHRC Anthony Ojukwu ati ajọ ajafẹtọ kan ti orukọ rẹ njẹ CACOL ni afihan aikun oju iwọn ijọba lati kapa iwa igbesunmọmi lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ajọ mejeji yii ni wọnke si aarẹ pe idaniloju ẹnu ni gbogbo igba ko lee tan ọrọ to wa nilẹ yii ju ki ijọba san ṣokoto rẹ ko le lati koju awọn ikọlu ati ipaniyan gbogbo to n ko ẹmi lọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Ile ti wọn kolu pẹlu lọpaa kan ti o n yọju wo inu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, CAN ni ko si iwulo fun iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ awọn ajọ alaabo bi o ba lee ṣeeṣe fun awọn amokunṣika lati pa ọpọlọpọ eeyan

Amọṣa, igbakeji aarẹ Yẹmi Oṣinbajọ ti ṣapejuwe ikọlu naa gẹgẹbii eyi to buru jọjọ pẹlu idaniloju pe iṣẹ ti n lọ labẹnu lati ko awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa.

Ileeṣẹ ọmọogun pẹlu ni awọn ti ko alekun akọṣẹmọṣẹ ọmọ ogun lọ si ipinlẹ Plateau.