Election Update 2019: Ohun márùn-ún tí Atiku ń bèrè lọ́wọ́ Buhari

Abdulsalami Abubakar ati Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, NIyi Daram

Lara ọpọlọpọ ọrọ to sọ, kókó ọrọ márùn-ún ni Atiku Abubakar ń bere fun lọwọ ijọba aarẹ Muhammadu Buhari eyi to gbe kalẹ fun ajọgbeyẹwo niwaju awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP.

Oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic party, Alhaji Atiku Abubakar ṣepade pẹlu Ọgagun Abdulsalami Abubakar, Biṣọọbu ijọ Katoliki ni Sokoto, Matthew Kukah atawọn mii ti wọn jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ fun alafia.

Bi o tilẹ jẹ pe atilẹkun mọri ṣe ni ipade naa, awọn oniroyin to wa nibi ipade naa sọ pe awọn koko ọrọ ti Alhaji Atiku Abubakar tẹpẹlẹ mọ ni:

  • Kí wọn ṣi asuwọn owo awọn oloṣelu alatako ti wọn gbe onte le ki wọn si da ẹtọ ṣiṣe katakara owo wọn nile ifowopamọ si.
  • Ki wọn ma sọ awọn eto idibo mii to n bọ lọna di idibo ijọba ologun.
  • Ṣiṣe ayẹwo orukọ awọn oludibo ki idibo gangan to bẹrẹ.
  • Ki ajọ INEC faaye gba gbogbo ẹgbẹ oṣelu to ba n kopa bo ṣe tọ lati mọ ohun ti wọn ba fẹ.
  • Ki wọn tu awọn oloṣelu ti ijọba apapọ fi si ahamọ lọna aitọ silẹ

Lalẹ ọjọbọ ọjọ kejidinlọgbọn oṣu keji ọdun 2019 ni ipade atilẹkun mọri ṣe naa waye lori idibo aarẹ ti wọn ṣẹdi tan lọjọ abamẹta to kogba wọle.

Àkọlé fídíò, 'Mẹ̀kúnù á rí iṣẹ́ tí mo bá di gómìnà Eko' - Adesanya, PPC Eko

Bakan naa, igbakeji fun Atiku, Peter Obi, aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Bukola Saraki, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Uche Secondus, Cardinal John Onaiyekan, Fada Atta Barkindo atawọn adari gbẹ oṣelu PDP mii naa peju sibẹ.

Igbimọ naa ni awọn ti gbọ ohun to da ọkan ẹgbẹ oṣelu PDP laamu awọn yoo si kan si ẹgbẹ oṣelu APC naa nitori ohun to tọ lati ṣe ninu iru iṣẹlẹ yii niyii.

mọ to n ri si alafia pẹlu igbakeji aarẹ

Oríṣun àwòrán, @AsoRock

Àkọlé àwòrán, Igbimọ to n ri si alafia pẹlu igbakeji aarẹ

Iroyin tun tẹ wa lọwọ pe igbimọ naa ṣi ṣe ipade kan pẹlu igbakeji aarẹ, ọjọgbọn Yemi Oṣinbajo lọjọbọ kan naa lẹyin ti wọn pari eyi ti wọn ṣe pẹlu Atiku Abubakar.