Election Update 2019: Inec kéde ọ́jọ́ kẹsàn oṣù kẹ̀ta fún àfikún ìdìbò ààrẹ

INEC

Oríṣun àwòrán, InEC

Àkọlé àwòrán, Afikun idibo

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria ti afikun idibo aarẹ yoo waye lọjọ Abamẹta ọsẹ to n bọ tii ṣe ọjẹ kẹsan oṣu kẹta.

Afikun idibo aarẹ yoo waye lọjọ kan naa pẹlu idibo gomina ati tile aṣofin ipinlẹ.

Ọga ajọ INec to n ri si ọrọ iroyin ati ilanilọyẹ awọn oludibo, Festus Okoye salayẹ pe idibo aarẹ naa yoo waye nibi gbogbo ti ajọ Inec ti wọgile ibo aarẹ lọjọ Satide to kọ ja.

O fikun ọrọ rẹ pe igbesẹ naa waye nibi ipade awọn ọga Inec ti ipinlẹ kọọkan l'Abuja.

Ajọ Inec ko le ran awọn oṣisẹ rẹ lọ si awọn ibudo idibo kan nitori rukerudo to bẹ silẹ lawọn agbegbe ọhun.