Election Update 2019: Amẹ́ríkà fí ọ̀rọ̀ ìkíni ránṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari

Trump ati Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Buhari ati Aarẹ́ Trump nibi ipade wọn to waye nile ijọba Amẹrika lọgbọn ọjọ osu kẹrin ọdun 2018

Tọtun tosi ni ojo ikini ti n rọ lori ijọba Naijiria fun aṣeyọri rẹ ninu idibo aarẹ to waye loṣu to kọja.

Lara awọn ta tun gbọ pe wọn fi ikini ranṣẹ ni orileede Amẹrika to ki aarẹ Buhari ku oriire iyansipo rẹ lẹẹkan si.

Ninu atẹjade kan ti akọwe agba orilẹede naa Micheal Pompeo buwọlu, Amẹrika nanwọ ikini yii si awọn eeyan orileede Naijiria fun bi ibo naa ti ṣe lọ ni irọwọ rọse.

Bakanna ni o bu ẹnu atẹ lu awọn janduku ti iwa jagidijagan wọn ko ipalara ba eto idibo naa.

O tẹsiwaju pe awọn ''ṣe akiyesi agbeyẹwo ti awọn onwoye eto idibo nile ati lati okere ṣe eleyi ti wọn ni eto idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ botilẹ́ jẹ wi pe awọn kudiẹ kudiẹ kan si wa.''

O ni awọn tun ki awọn oludije ''to kopa ninu idibo naa ni pẹlẹ kutu''

Lakotan Amẹrika ni awọn rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati ri wi pe idibo gomina to n bọ lọna naa lọ lẹrọwọ.

O ni Amẹrika yoo si ma pawọpọ pẹlu Naijiria lati mu alafia ati idagbasoke ba awọn orilẹede mejeeji.