'Ìdí tí awọn ilú okèèrè ko ṣe lè yọwọ́ kúrò nínú ìdìbò Naijiria?'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọrọ bi awọn orilẹ-ede miiran ṣe n da si ọrọ idibo àti ọ̀rọ̀ abẹ́le Naijiria ti mu oriṣiriṣi aawọ wa laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC ni Naijiria.
Ṣugbọn ajafẹtọ-ọmọniyan kan, Omololu Akinwande ti ni bi ọmọde ni Naijria jẹ, awọn orilẹ-ede to jẹ agbaagba ninu ijọba awa arawa ni agbaye ko le ṣe alaidasi ọrọ idibo Naijiria.
Bi ijọba apapọ Naijiria ṣe n pariwo pe awọn ko fẹ ki awọn orilẹ-ede miiran da si idibo Naijiria ni ẹgbẹ oṣelu PDP ni ko si ohun to buru nibẹ.
Wọn tún bẹnu ẹ̀tẹ́ lu bi awọn gomina meji lati orilẹ-ede Niger ṣe wa si ibi ipolongo ibo ẹgbẹ APC ni oṣu kinni ọdun yii.

Ni Ọjọbọ, Gomina Ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ke pe orilẹ-ede Amerika lati da si eto idibo gomina Naijiria to n bọ lọna lati le dẹkun bi awọn kan ṣe n halẹ mọ awọn oludibo.
Akinwande ni idi ti ko ṣe si ohun to buru ninu ipe Tambuwal yii ni wi pe, orilẹ-ede Naijiria ti bẹrẹ si ni ṣe ohun to tọ.
Nigbogbo idibo ni ijọba orilẹ-ede Amerika, EU ati Ilẹ Gẹẹsi maa n ran awọn onwoye wa.
Ọgbẹni Akinwande sọ fun BBC News Yoruba pe ọpọlọpọ nkan ni ko ba ti aye mu to n ṣẹlẹ ni orilẹ-ede Naijiria.
O ni idi ree ti awọn orilẹ-ede to ku ko fi gbọdọ jawọ ninu ọrọ abẹle Naijiria bo ti lẹ jẹ pe o yẹ ko mọ ni iwọnba.
O ni ijọba awa arawa ni Naijiria nilo amojuto.
Ati pé ni ayọnusi ti awọn orilẹede okeere n ṣe lori idibo Naijiria kii ṣe wipe lati fi ifẹ ara wọn ṣe lori orilẹede yii ni bi ko ṣe wipe lati ri pe gbogbo nkan lọ deedee.

Ajafẹtọ naa ni ọkan lara awọn nkan gboogi ti agbaye maa fi mọ wipe nkan ko lọ deede lori idibo Naijiria ni wipe, awọn to ṣe iforukọsilẹ idibo le ni ọgọrin miliọnu, awọn to gba kaadi ju aadọrin miliọnu, ṣugbọn awọn to dibo ko to ọgbọn miliọnu eniyan.
O ṣalaye wipe nigba ti orilẹede yii ba bẹrẹ si ni ṣe oun to tọ, wọn le wa ni ki awọn orilẹede miiran ma da si ọrọ idibo Naijiria.













