Nigeria 2019: Amẹrika, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò ní ààyò olùdíje fún ààrẹ
Oríṣun àwòrán, News4c
Awọn aṣoju orilẹ-ede Amẹrika ati Ilẹ Gẹẹsi ni Nigeria ti ni awọn ko ni aayo kankan lara awọn oludije fun ipo aarẹ ninu idibo ọdun 2019 ti yoo waye ni oṣu keji.
Awọn ileeṣẹ orilẹ-ede mejeeji ni Naijiria jijọ gbe atẹjade kan sita ni Ọjọbọ ninu eyi ti wọn ti ni awọn yoo yan ọpọlọpọ awọn onwoye tí yoo lọ kakakiri awọn ibi idibo lọjọ idibo aarẹ.
Awọn aṣoju orilẹ-ede Amẹrika ni eto idibo to lọ wọrọwọ ti ko si mu wahala dani lo jẹ awọn logun. Wọn ni awọn orilẹ-ede oni ijọba awa-arawa ti n woye bi awọn kan ṣe fẹ fa wahala lakoko idibo naa.