ACPN: Ìdí tí ẹgbẹ́ wa fi padà lẹ́yìn Ezekwesili

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ ti olùdíje obinrin si ipo aarẹ tẹlẹ ri, Oby Ezekwesili ti n dupo, Allied Congress Party of Nigeria (ACPN) ti yọwọ lawo ṣiṣe atilẹyin fun Ezekwesili.
Ni bayii, ẹgbẹ naa ti ṣi lọ sẹyin aarẹ Muhammadu Buhari ti ẹgbẹ oṣelu All People's Congress wọn si ni awọn fọwọ si ki aarẹ Buhari maa baṣẹ lọ.
Nigba ti BBC Yoruba ba alaga ẹgbẹ oṣelu ACPN, Alhaji Ganiyu O. Galadima sọrọ, o j ko di mimọ pe otitọ ni pe awọn ti pada lẹyin arabinrin Ezekwesili
Ẹgbẹ́ ACPN ti ṣáájú fii hande ninu atẹjade ti ẹgbẹ oṣelu fi sita pe Oby Ezekwesili kan ran kankan mọ ipolongo lasan ni lai ni alakalẹ kankan nilẹ.

Alhaji Ganiyu sọ pe latẹnu oluranlọwọ Oby ni awọn ti ko aridaju jọ wi pe gbogbo ilakaka rẹ lati ọjọ yii kii ṣe lati di aarẹ gan bi ko ṣe lati san ọna dide ipo minisita fun eto isuna.
O ni nibi ipade oniroyin to waye gan, bi Oby ṣe fi ipinu rẹ han j ohun ti o ti ro tẹlẹ ni.
Lowurọ ọjọbọ ni Oby Ezekwesili kede ipinu rẹ lati ma dupo aarẹ mọ lori oniruuru atẹjade rẹ ni ikanni Twitter.









