Dora Akunyili, Ngozi Okonjo-Iwealla, Oby Ezekwesili: Òbìnrin mánigbàgbé mẹ́ta nínú ìjọba tiwantiwa láti odún 1999

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati ọdun 1999 ti orilẹ-ede Naijiria ti pada si iṣejọba tiwantiwa, oniruru awọn obinrin lo ti ṣa ipa ti wọn ninu idagbasoke iṣejọba tiwantiwa ti gbogbo agbaye si mọ kale-kako.
Mẹta ninu wọn ree.
Awọn obinrin ti ina orukọ wọn ko fi igba kan ku lati igba ti iṣejọba tiwantiwa ti bẹrẹ.
- Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun
- Wo àwọn ohun méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngozi Okonjo-Iwealla àti ọkọ rẹ̀ Ikemba
- Irọ́ ni pé wọ́n ti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kagara sílẹ̀- Gomina ìpínlẹ̀ Niger
- Ṣé lóòtó ni ilé-iṣẹ́ ológun gbé hẹlikópítà ìjagun lọ si Orlu ní ìpínlẹ̀ Imo?
- Irọ́ ni o, mí o fẹ̀ Lafeet Adedemeji- Oyin Elebuibọn pẹ̀lú omijé ojú
- Mo pàdánù owó tó lé ní N20m lọ́jà Shasha, mi ò padà síbẹ́ mọ́- Alhaji Nyako

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oloogbe Ọjọgbọn Dora Akunyili
Ọjọgbọn Dora Akunyili jẹ ọmọ ipinlẹ Anambra, ṣugbọn ilu Markurdi ni ipinlẹ Benue ni wọn bii si ni ọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun 1954.
Igba ti o di ilumọọka fun awọn ọmọ orrilẹ-ede yii ni asiko ti aarẹ orilẹ-ede nigba naa, Oluṣẹgun Ọbasanjọ yan an gẹgẹ bii oludari agba fun ajọ to n gbogun ti ilokulo ounjẹ, ohun mimu ati ogun ni Nijiria, NAFDAC laarin ọdun 2001 si 2008.
Aṣeyọri ti Ọjọgbọn Dora Akunyili ṣe lasiko naa kuro ni kekere nitori oun lo mu igba ọtun wọ eto gbigbogun ti ayederu oogun oloro lorilẹ-ede Naijiria nigba naa.
Koda, awọn awujọ agbaye gbogbo ni wọn kan sara si fun iṣẹ takuntakun ti o ṣe nigba naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Labẹ iṣejọba aarẹ Naijiria ti o di oloogbe, Musa Yaradua ni wọn ti yan an gẹgẹ bii minisita fun eto iroyin ati ibanisọrọ lọdun 2008 si 2010.
Lasiko ti aarẹ Yaradua di oloogbe, ti igbakeji rẹ, Goodluck Jonathan si rọpo rẹ, yii gan an ni Dora Akunyili gbe akanṣe eto kan kalẹ to pe ni 'Re-branding Nigeria Project' fun atunṣe orukọ ati iyi orilẹ-ede Naijiria.
Nigba naa ni o gbe akori, Nigeria...good people, great nation jade.
O dije dupo senetọ ni Anambra Central lọdun 2011 ṣugbọn Chris Ngige lo gbegba oroke.
Dora Akunyili jade laye lọdun lọjọ keje, oṣu kẹfa, ọdun 2014 lẹyin to kopa ninu apero itesiwaju Naijiria CONFAB.
wọn sin in ni ọjọ ketadinlogun ati ikejidinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2014.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu idanilẹkọ kan ti o ṣe ni ilu Eko ni ibẹrẹ ọdun 2018, aarẹ ana Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni, eeyan kan to gburo iwa olootọ Dora lasiko to fi wa ni ileewe kan ni ilẹ Gẹẹsi lo fi ọrọ rẹ to oun leti ti oun fi yan an.
Lẹyin ti o kuro ni ijọba, Ọjọgbọn Dora Akunyili wa lara awọn ti wọn yan fun igbimọ apero ti ijọba apaps gbe kalẹ fun agbeyẹwo ẹhonu awọn ẹya lorilẹede Naijiria.
Akunyili ku ni ọjọ keje oṣu kẹfa ọdun 2014 lẹyin to ba aisan jẹjẹrẹ finra fun ọpọlọpọ igba.

Oríṣun àwòrán, @NOIweala
Ọjọgbọn Ngozi Okonjo-Iweala
Ọjọgbọn Ngozi Okonjo-Iweala jẹ minisita ijọba meji lorilẹede Naijiria-2003 si 2006 labẹ aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ, 2011 si 2015 labẹ iṣejọba aarẹ Goddluck Jonathan.
Banki agbaye ni Ọjọgbọn Ngozi Okonjo-Iweala ti n ṣiṣẹ ki aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ to pe e wa sile.
O ni ko wa ṣe minisita fun eto iṣuna lorilẹ-ede Naijiria oun ni obinrin akọkọ ti yoo ṣe minisita fun eto iṣuna ati minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹ-ede Naijiria.
- Alhaja Muslimot Salami tí àwọn darandaran kọlù ní Ogun tí padà jẹ́ Olorun nípè!
- A kò tíì gbọ́ pé ilé ẹjọ́ wọ́gilé gbígba owó lọ́wọ́ àwọn dẹ́rẹ́bà ni ibudokọ ipinlẹ Oyo- awọn Awakọ̀
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
- Kí ló mú kí géńdé Olorun fi àfọ́kù ìgò gé ǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ ní Kano?
- Ìjọba Naijiria ti kùnà lórí ojúṣe rẹ̀ lóri ètò aàbò- Bode George

Oríṣun àwòrán, @NOIweala
Ọkan lara awọn eekan to lagbara labẹ iṣejọba aarẹ Ọbasanjọ laarin ọdun 2003 si 2006 ni Okonjo-Iweala.
O si ko ipa ribiribi ninu bi awọn igbimọ orilẹ-ede agba kan lagbaye ṣe wọgile gbese biliọnu mejidinlogun dọla, $18bn ti orilẹ-ede Naijiria jẹ ṣaaju igba naa.
Pupọ ọmọ orile-ede Naijiria ni ko ni gbagbe minisita 'alaṣọ ankara' yii pẹlu gele 'ipakọ o gbọ ṣuti' rẹ.
Bayii, Ngozi Okonjo-Iwealla ti di oludari ajọ olokowo agbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọwe Obiageli "Oby" Ezekweseli
Ohun ti ọpọ awọn ọdọ mọ Obiageli Ezekwesili fun ni ipa rẹ gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ to n ja fun itusilẹ awọn akẹkọọ ileewe girama kan ni Chibok ipinlẹ Borno.
Awọn ni awọn ọmọ-ogun Boko haram ji gbe ni ọdun 2014, #BringBackourGirls.
Bakan naa lo tun lewaju ẹgbẹ kan to n ja fun ilana iṣejọba rere, 'Red Card'
Lara awọn ipo ti o ti di mu ninu iṣejọba orilẹ-ede Naijiria lati igba ti saa iṣejọba tiwantiwa yii ti bẹrẹ ni amugbalẹgbẹ pataki fun aarẹ Ọbasanjọ lori amojuto iwe eto iṣuna, minisita fun ohun alumọni ati minisita feto ẹkọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lasiko to fi jẹ minisita feto ẹkọ ni Oby, gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n pe e, ṣe eto atunto ẹka eto ẹkọ lorilẹ-ede Naijiria ninu eyi ti spọ awọn orilẹede Afirika mira ti ya lo bayii.
Oniruuru awọn aarẹ orilẹ-ede Afirika ni o ti ṣiṣẹ fun gẹgẹ bii olubadamọran ptataki.
Ni bayii, Ọmọwe Oby Ezekwesili ni oludije ipo arẹ fun ẹgbẹ oṣelu Allied Congress Party of Nigeria, ACPN fun idibo apapọ ọdun 2019 lorilẹ-ede Naijiria.















