Aláboyún: Fọ́tò ọmọ ìyá mẹ́ta tí wọ́n lóyún lu ayélujára pa

Ankoo aṣọ wiwọ la saba maa n ri laarin awọn eniyan.
Sugbọn oriṣiriṣi ara lawọn eeyan n da nisinyi, eyi lo difa fun awọn ọmọbinrin mẹta yii Chika Okafor, Ogechi Babalola ati Onyeka Ufere ti wọn ko anko oyun.
Koda fọto awọn mẹtẹẹta nibi ti wọn ti n rẹrin pẹlu oyun ninu wọn ti lu oju opo ayelujara pa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 'Mi ò mọ̀ pé mo lóyún àfìgbà t'ọ́mọ ń rún'ra'
- Àwọn dókítà ya ìbejì tó lẹ̀pọ̀ l'Abuja
- Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ṣáájú ìdìbò abẹ́nú gómìnà ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Osun lọ́la
- Wo àwọn ewu àti ànfàní márùn ún tó wà nínú igbó mímu
- "Ó ṣeéṣe kí wọ́n ti ṣe àyípadà àti àtúnṣe sí fọ́nrán tí wọ́n gbé jáde lórí ọ̀rọ̀ Bàbá Ijesha"
- Ààrẹ Mozambique tẹ́lẹ̀ rí jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan ọmọ rẹ̀
Ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni awọn obinrin mẹtẹẹta yii, ṣugbọn ilẹ Amẹrika ni wọn fi ṣe ibugbe bayii.
Ẹgbọn patapata laarin awọn mẹtẹẹta Onyeka ni ẹni akọkọ ninu fọto wọn ti Chika si wa laarin nigba ti Ogechi ti o kere julọ ninu wọn duro sapa ọtun.
Ohun to yani lẹnu ni pe asiko kan naa lawọn mẹtẹẹta loyun si.









