Marijuana Use: Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàlàyé ewu àti ànfàní tó wà nínúi igbó mímu

Marijuana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Egboogi igbo jẹ okan lara awọn egboogi ti ijọba apapọ ti gbẹsẹle ni Naijiria, ọpọ awọn ọdọ lo si ti wa ni ahamọ nitori pe wọn n mu egbogi naa.

Amọ atimọle yii ko tii di ọpọ eeyan mii lọwọ lati fi egboogi naa silẹ.

Lootọ ni awọn onimọ ijinlẹ sọ pe igbo ni anfanni to n ṣe fun agọ ara, amọ, egboogi naa tun ni awọn ewu kan ninu, idi rẹ ti ijọba aapọ ṣe gbẹsẹle, ti ajọ NDLEA si n fi ṣikun ofin mu awọn to n ta, tabi ti wọn n mu.

Anfani to wa ni igbo

Awọn onimọ ijinlẹ so pe igbo wulo lati wo awọn asisan ninu agọ ara eeyan.

Onimọ ijinlẹ kan, Ọjọgbọn Makuochi Muobike sọ fun BBC pe igbo dara fun awọn to ni aisan ti wọn n pe ni "post-traumatic stress disorder" ati arun "Parkinson."

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn

Dokita miran, Udodi Okoli sọ pe igbo maa n ran awọn ti kii ri orun sun lọwọ lati sun daadaa

Amọ oni dokita nikan lo yẹ ko sọ iye iwọn igbo ti eeyan le mu nitori ilera ara rẹ nigbakugba.

O ni "Bo tilẹ jẹ pe igbo ni anfaani to pọ, kii ṣe ogun to yẹ ki dokita sọ pe ki alaisan lọ lo nitori aṣilo rẹ."

Àkọlé fídíò, Segun iberu

Ewu to wa ninu igbo minu

Awọn ewu wọnyin ni awọn onimọ ijinlẹ ti sọ pe o wa ninu igbo amuju.

  • O le di baraku
Marijuana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • O le ṣakoba fun ọpọlọ ẹda
  • O le ṣakoba fun awọn eya ara, paapaa awọn ẹya to wa ninu
  • Igbo mimu le sọ eeyan di ẹlẹwọn - eyii ko ṣẹyin bi ijọba apapọ ṣe fofin de lilo ati tita rẹ ni Naijiira
Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'

Ki ni ofin Naijiria sọ nipa igbo mimu?

Ajọ NDELA ni ajọ ti ijọba apapọ fun ni agbara lati gbogun ti igbo mimu, ati awọn egboogi oloro mii.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Ijiya fun ẹnikẹni ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori ni ẹwọn ti iye rẹ to ọdun mejila.

Bo tilẹ pe awọn ajọ ati oloṣelu kan ti n sọ pe ki ijọba Naijiria ka ofin to fi de igbi mimu kuro nilẹ, amọ ijọba apapọ ti kọ lati ṣe bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Agbẹdẹ Adodo