Mozambique corruption trial: Ààrẹ àná Armando Guebuza jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí wọ́n fi kan ọmọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Yoruba bọ, wọn ni iyan ogun ọdun a maa jo ni lọwọ.
Bayii ni ọrọ ri pẹlu aarẹ ana orilẹede Mozambique, Armando Guebuza to lọ sọ tẹnu rẹ ninu igbẹjọ iwa ajebanu ọmọkùnrin rẹ.
Guebuza to jẹ aarẹ Mozambique akọkọ ti yoo jẹrìí nile ẹjọ ṣalaye idi ti ijọba rẹ fi ya biliọnu meji dọla lati fi se ọsin ẹja.
- Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil
- Olaleye Paul rí ẹ̀wọ̀n he ní àyájọ́ olólùfẹ́ ní Ilọrin
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè
- Afurasí tọkọtaya ta ẹ̀yà ara ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà- Ọlọ́pàá
- Àgbáríjọpọ̀ èèyàn sẹkúpa ọkùnrin kan lórí ẹ̀sùn pé ó dáná sun Kurani
- Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ọmọ ọdún kan àti oṣù méje pa ní ìpínlẹ̀ Delta, O bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
Ni ọpọ igba ni wọn mu ina lasiko ti Guebuza n sọrọ lọwọ ti awọn araalu si n wo o lori tẹlifísàn.
Guebuza to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogorin sọ fun lati ma mẹnu ba ẹrọ eto abo nitori ko si labẹ wọn.
-Ẹsun ti wọn fi kan ọmọ Aarẹ Mozambique tẹlẹ rí ree
Ndambi to jẹ ọmọ aarẹ Mozambique tẹlẹ ri wa lara eeyan mọkandinlogun ti fẹsun kan pe wọn lo ẹyawo ẹẹdẹgbeta mílíọ̀nù dọla ($500m) fun nkan mii eleyii ti ile aṣofin ko mọ si.
Ndambi ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn kan oun pe oun gba riba lati sọ fun baba oun pe ki o buwọlu ẹyawo idakọnkọ ati akanṣe iṣẹ ori omi.
Ndambi joko nile ẹjọ pẹlu asọ awọn ẹlẹwọn lọrun rẹ nigba ti baba n jẹri.
Ndambi ti wa ni atimọle lati ọdun 2019.
Nigba ti aṣiri ẹyawo naa tu sita, awọn ajọ ayani-lowo lagbaaye dawọ iranwọ wọn duro eleyii to koba owo Mozambique ati ọrọ aje ilẹ naa pẹlu.





















