Brazil flodding: Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kere tan eeyan mejidinlogoji ni omi ti gbe lọ lorilẹede Brazil.
Awọn oṣisẹ adoola ẹmi lasiko pajawiri ṣalaye pe ẹkun omi ọhun lo ṣe okunfa bi ilẹ ṣe n ya lu awọn eeyan ti wọn si gba ibẹ ku.
Ni Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun oṣi keji ọdun 2022 ni iṣẹlẹ ọhun ṣelẹ ti wọn si n ka iye awọn to ba ijamba naa rin niluu Petrópolis.
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè
- Afurasí tọkọtaya ta ẹ̀yà ara ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà- Ọlọ́pàá
- Awakọ̀ dáná sun ara rẹ̀ lórí bí àwọn 'task force' ṣe mu l'Eko
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Àgbáríjọpọ̀ èèyàn sẹkúpa ọkùnrin kan lórí ẹ̀sùn pé ó dáná sun Kurani
- Àwọn tọ́ọ̀gì Aregbesola ló da wàhálà sílẹ̀ l'Osun - Ọlọ́pàá
Ojo nla kan lo rọ niluu naa to wa laarin awọn oke lapa ariwa ilu Rio de Janeiro.
Gbogbo ile to wa lori oke niluu naa lo wo lulẹ.
Koda, omi tun ru ọpọlọpọ ọkọ ti wọn gbe silẹ lọ lasiko ẹkun omi naa.
Adari ijọba ilu ọhun ti kede ofin ilu o fara rọ lẹyin iṣẹlẹ naa.
Awọn fidio tawọn eeyan fi sori ayelujara fihan pe nkan ti ẹkun omi ọhun bajẹ pọju.
Koda, awọn bọọsi nla to tobi gan an ni omi naa ru lọ.
Aarẹ Jair Bolsonaro to wa ni Russia nigba ti iṣẹlẹ ọhun sẹlẹ ṣeleri iranwọ fawọn ti o fara kaasa ninu iṣẹlẹ naa.
Awọn sọja to le ni ọgọsan ni wọn ti lọ silu naa nibi ti wọn ti n wa awọn eeyan.
Ile bi ọgọrin ni a gbọ pe ẹkun omi ọhun bajẹ niluu Petrópolis.
Iru iṣẹlẹ saaba wọpọ niluu ọhun, koda ẹẹdẹgbẹrun eeyan lo ku ninu iru isẹlẹ ọhun to ṣẹlẹ lọdun 2011
















