Patrick Kimaro: Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè

Iboji Patrick Kimaro

Ko si ẹni ti ko ni ku, bo pẹ bo ya onilkaluku maa dagbere fun aye lọjọ kan.

Adifa fun ọkunrin kan, Patrick Kimaro, lorilẹede Tanzania to ti kọ iboji to fẹ ki wọn sin in sinu rẹ nigba ti o ba ku tan.

Ọgbẹni Kimaro, ẹni ọdun mọkandinlọgọta, sọ pe awọn ẹbi oun ti n gba pẹlu oun bayii lori igbesẹ oun.

Kinni awọn araalu Patrick Kimaro sọ lori iboji rẹ to gbẹ silẹ?

Ọpọ awọn araalu Kimaro ni wọn koro oju si igbesẹ rẹ lati gbẹ iboji rẹ silẹ nigba ti o si wa laaye.

Ọpọ awọn olori ẹya Kilimanjaro to jẹ ẹya Kimaro sọ pe nkan buruku ni ki eeyan gbẹ iboju rẹ silẹ nigba ti ko tii ku.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Igbagbọ awọn eeyan naa ni pe ko yẹ ki iboju wa nilẹ fun ọjọ pipẹ.

Ọgbẹni Kimaro to jẹ ọlọpaa sọ fun BBC pe oun bẹrẹ si ni kọ ile naa ninu oṣu kinni.

Kimaro ni oun gbe igbesẹ lati gbẹ iboji oun lati le din inawo oku ṣiṣe ku fawọn ẹbi oun nigba ti oun ba dagbere faye.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Patrick Kimaro ṣalaye idi to fi gbẹ iboji rẹ

Kimaro ni nigba ti oun wa ni kekere, o nira fun oun lati sin baba ati mama oun tori oṣu mẹfa ni wọn ku sira wọn.

''Eyi lo jẹ ki n pinnu lati gbẹ iboji mi silẹ tori mi o fẹ fun awọn ọmọ wọn ni wahala ti mo ba ku,'' Kimaro lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Kimaro ti ya owo sọtọ fun posi rẹ, o gbagbọ pe awọn ẹbi rẹ yoo le wa owo lati ṣe awọn nkan mii to ba ku.

Koda, o tun n ronu lati ṣe eto adojutofo fun iboji rẹ nitori ti ijamba bi ẹkun omi ba ṣẹlẹ nibẹ.

Iboji Patrick Kimaro

$3,000 tii ṣe owo to le ni miliọnu kan naira ni Kimaro fi kọ iboji rẹ naa.

Ọpọ eeyan ni ko le wa si ile Kimaro mọ nitori iboji ara rẹ to kọ si ile rẹ.

Ṣugbọn o ti mọ awọn ẹbi rẹ lara, koda, awọn miran ninu maa n joko si eti iboji naa.