Tafa Oloyede: Tìlù-tìfọn ni ẹbí àti àwọn gbajúmọ̀ òṣèré fi si òkú John Adewuni

Tafa Oloyede ati Posi rẹ

Ọjọ́ kan làá joyin, ọjọ́ kan làá jàdò, ọjọ́ kan la ó sún tá ò ní jí mọ́, tí iná yóò dilẹ̀ lẹ́yìn asunsunjẹ.

Òkú onípósí a máa lo ogún ọdún, òkú onípàkìtì a lo ọgbọ̀n oṣù, òkú ọlọ́mọ àsinǹsintán.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, John Adewumi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Tafa Oloyede ti wọ káà ilẹ̀ sùn.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlá, ọdún 2022 ní ìsìnkú olóògbè náà wáyé ní ìlú abínibí rẹ̀, ìlú Ede, ìpínlẹ̀ Osun.

Ẹ tun igbesẹ aye yin se, kẹ le de ijọba ọrun - Oniwaasu

Níbi orin ìyìn ìdágbére tó wáyé ní ilé ìjọsìn ìjọ Onítẹ̀bọmi, Iseki Akala, Ẹni ọ̀wọ̀ Gbenga Olorode rán àwọn ènìyàn létí pé awáyé mákùú kan ò sí, gbogbo ẹni tó ń ṣẹ̀mí ni yóò tọ́ ikú wò.

Ẹni ọ̀wọ̀ Olorode ní olóògbé John Adewumi ti gbé ìgbé ayé tó sì ti lọ sinmi láyà Olùgbàlà báyìí níbi tí yóò ti jábọ̀ ohun tó gbé ilé ayé ṣe.

Pásítọ̀ náà rán àwọn ènìyàn létí pé wọ́n ní àǹfàní láti tún ìgbésẹ̀ wọn ṣe, kí wọ́n sì máa rin ọ̀nà tó tọ́ lójúnà à ti rí ìjọba ọ̀run.

Bákan náà ló rọ àwọn ọ̀dọ̀ láti nífẹ̀ẹ́ ohun ayé mọ ní wọ̀n, kí wọ́n má ba ṣi ayé gbé, àti pé ohun tí yóò tán ni gbogbo rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà lo pàrọwà sí àwọn ẹbí olóògbé láti wà ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n sì mójútó gbogbo dúkìá tí olóògbé fi sáyé lọ dáradára.

Lẹ́yìn ò rẹyìn ní òkú John Adewumi wọ káà ilẹ̀ sùn ní itẹ́ òkú ìjọ Onítẹ̀bọmi ní nǹkan bí ago mẹ́ta kọjá ìṣẹ́jú márùndínlọ́gbọ́n ọ̀sán níbi tí ẹbí, ará àti àwọn ọ̀rẹ́ ti kọrin arò lẹ́yìn rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Àwọn ọmọde tí mò ń bá ṣe ‘skit’ ló dáwó jọ fún mi nígbà tí àìsàn inú dé sí mi

Gbajúgbajà òṣèré tíátà Tafa Oloyede dágbére fáyé:

Kò sí bó ti wù ká gbajúmọ̀ tó nílè ayé tàbí kí a là kàkà tó, ọjọ́ ọjọ́ kan la ó ṣe dúnìyàn lódìgbà.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, John Adewumi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Tafa Oloyede ti dágbére fáyé.

Lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ni Tafa Oloyede mí mímí ìkẹyìn ní ilé rẹ̀ tó wà ní Arowomole, Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun, lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.

Oloyede, tó di gbajúgbajà òṣèré lẹ́yìn tó kópa nínú eré Akanji Oniposi, fi ìyàwó àti àwọn ọmọ sáyé lọ.

Amin iyasọtọ kan

TAMPAN ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Tafa Oloyede bí ètò ìsìnkú rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀:

Ikede isinku Tafa Oloyede

Oríṣun àwòrán, TAMPAN Osun

Awaye ku ko si, ko si ẹni ti ko ni ku, ko si ẹni ti oko baba rẹ ko ni di igboro.

Eto isinku agba osere tiata ni ede Yoruba, John Adewuni Adewoye, ti ọpọ eeyan mọ si Tafa Oloyede ti bẹrẹ loni.

Eto isinku naa ni awọn mọlẹbi ti kede saaju pe yoo bẹrẹ lonii ọjọbọ ọjọ Kẹwaa osu keji ọdun 2022, ti yoo si wa sopin lọla ọjọ Ẹti.

Atẹjade kan ti ẹgbẹ awọn osere tiata, ẹka ti TAMPAN ni ipinlẹ Osun fisita, ti wa kede bi eto isinku naa yoo ti maa waye.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa

Bi eto isinku Tafa Oloyede yoo se lọ:

Ọjọbọ ọjọ Kẹwaa osu Keji ọdun 2022:

Se bi ọdẹ ba ku, ọdẹ lo maa n se oro lẹyin ọdẹ, wọn ni bi ina ku, yoo fi eru boju, bi ọgẹdẹ ku, yoo fi ọmọ rọpọ ara rẹ.

Awọn osere tiata ti wọn jẹ akẹẹgbẹ oloogbe Tafa Oloyede ni yoo kọkọ side ilana eto isinku rẹ pẹlu eto imọyi awọn osere tiata.

Eto imọyi naa ni wọn n pe ni Artistes Day, deede aago mejila ọsan si lo ti gbera sọ.

Agboole oloogbe Iseki Oloro to wa ni nilu Ede, tii se ilu Abinibi Tafa Oloyede ni eto naa ti n waye.

Ikede isinku Tafa Oloyede

Oríṣun àwòrán, TAMPAN Osun

Ọjọ Ẹti ọjọ Kọkanla osu Keji ọdun 2022:

Ọla ọjọ Ẹti ni eto isinku Tafa Oloyede yoo maa waye.

Ile ijọsin onitẹbọmi ti Iseki Oloro to wa nilu Ede si ni isin idagbere fun oloogbe naa yoo ti waye.

Aago mẹsan owurọ ni eto isin idagbere naa yoo bẹrẹ.

Lẹyin naa ni wọn yoo gbe oloogbe lọ si itẹ ijọ naa.

Bi eto isisnku naa ba si se n waye, ni BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin.

Ta ni Tafa Oloyede.

John Adewuni Adewoye, ni ọpọ eeyan mọ si Tafa Oloyede lori ere tiata.

O jẹ gbajumọ osere tiata lori mohunmaworan, sinima agbelewo ati fiimu ni ede Yoruba,

Ẹgbẹ osere Oyin Adejobi lo wa, to ti di ilumọọka osere tiata nilu Osogbo.

Ọmọ bibi ilu Ede ni Tafa Oloyede, to si ti kopa ninu ọpọ sinima, ere itage ati fiimu.

Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bíi Jayesinmi, Ayanmo, Ekuro Oloja, Orogun, Akanji Oniposi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Agba ọjẹ osere tiata ni, amọ to jade laye ni ẹni ọdun mọkandinlaadọta ni ọjọ Kinni osu Keji ọdun 2022.

Àkọlé fídíò, Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́