Tafa Oloyede: Bí ìsìnkú John Adewumi, àgbà òṣèré tíátà yóò ṣe lọ rèé

Oríṣun àwòrán, @Tafa Oloyede
Gbajúgbajà òṣèré John Adewumi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Tafa Oleyede tó jáde láyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, kìíní oṣù kejì yóò káà ilẹ̀ sùn lọ́jọ́ Ẹti, ọjọ́ kọkànlá oṣù kejì.
Gómìnà ẹgbẹ́ TAMPAN ní ìpínlẹ̀ Osun, Alhaji Moruf Lawal lo sọ èyí nílùú Osogbo.
Lawal ní àwọn tí parí gbogbo ètò pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé náà nipa bi isinku rẹ yoo se lọ.
- "Sunday Igboho yóò jáde ní àhámọ́ láìpẹ́, ariwo ayọ̀ yóò sọ nílẹ̀ Yorùbá"
- ''Ọjọ́ ti mo jẹ́ £127,000 nídìí tẹ́tẹ́, ni ogun ọjọ́ pípẹ́ bẹ̀rẹ̀ nínú ayé mi''
- Ta ni yoo gba ife ẹyẹ AFCON laarin Mane ati Salah?
- Ọbabìnrin Elizabeth kéde pé kí Camilla di ayaba tí ọkọ rẹ, Charles bá gun orí ìtẹ́
- Ènìyàn 24 dágbére fáyé, 9 farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abuja, Yobe
- Jaigbade Alao, àgbà ọ̀jẹ̀ olórin dadakuàdà tó fiṣẹ́ orin sílẹ̀ ní Ilorin lẹ́ni ọgọ́fà ọdún
Ó ní lọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹwàá osu keji ọdun 2022 ni ẹgbẹ́ àwọn osere tiata yóò ṣe ayẹyẹ idagbere fun, ta tun mọ si "Artist Day".
Ile rẹ to wa ní ìlú abinibi Tafa Oloyede, Ẹdẹ ni eto naa yoo ti maa waye bẹrẹ lati aago méjì ọ̀sán sí aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní alẹ́ àìsùn onígbàgbọ́ yóò wáyé lọ́jọ́bọ bákan náà, kí olóògbé tó máa lọ sinmi láyà olùgbàlà lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ kọkànlá.
Àwọn àgbà òṣere n ṣe idaro Tafa Oloyede to re ibi agba n re yii.
Gbajúgbajà òṣèré tíátà nì, John Adewumi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Tafa Oloyede dágbére fáyé
Jide Kosoko, Otunba Dodoede n selédè lẹ́yìn Tafa Oloyede tó kú
Ni kete ti iroyin iku oloogbe John Adewumi ni awọn agba oṣere bii Adebayo Bello ti ọpọ n pe ni Oga Bello ti n ṣe idaro rẹ .
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 1
Awon mii tun ni Otunba Adekunle Abolade Dodoede to mẹnuba awọn ere Oloogbe Tafa to gbadun bii Ayanmọ Ekuro ọlọja, Orogun, Akanji Oniposi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 2
- Mi ò kọ Atiku Abubakar nítorí pé o fẹ́ ìyàwó mìíràn- Jennifer Douglas Abubakar
- China sinmi lórí yíyá Nàìjíríà lówó, èyí lè fà ìdádúró lórí iṣẹ́ rélùwé
- Ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ wáyé ní orílẹ̀-èdè Guinea Bissau, wo ohun tí a lè fìdíẹ̀ múlẹ̀ nípa rẹ̀
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì tó ń fa shisha l'Ogun ti padà sílé ẹ̀kọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ lọ rọ́kùn ńlé
- 'Mílíìkì ni a fẹ́ máa fi ẹbu tí a bá ri lára orí Sofia ti a jó pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé á máa di olówó'
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
Ikú dóró: Gbajúgbajà òṣèré tíátà Tafa Oloyede dágbére fáyé
Kò sí bó ti wù ká gbajúmọ̀ tó nílè ayé tàbí kí a là kàkà tó, ọjọ́ ọjọ́ kan la ó ṣe dúnìyàn lódìgbà.
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, John Adewumi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Tafa Oloyede ti dágbére fáyé.

Oríṣun àwòrán, @Tafa Oloyede
Lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ni Tafa Oloyede mí mímí ìkẹyìn ní ilé rẹ̀ tó wà ní Arowomole, Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun, lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.
Oloyede, tó di gbajúgbajà òṣèré lẹ́yìn tó kópa nínú eré Akanji Oniposi, fi ìyàwó àti àwọn ọmọ sáyé lọ.
- Ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ wáyé ní orílẹ̀-èdè Guinea Bissau, wo ohun tí a lè fìdíẹ̀ múlẹ̀ nípa rẹ̀
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
- 'Mílíìkì ni a fẹ́ máa fi ẹbu tí a bá ri lára orí Sofia ti a jó pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé á máa di olówó'
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì tó ń fa shisha l'Ogun ti padà sílé ẹ̀kọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ lọ rọ́kùn ńlé
- Ààrẹ Muhammadu Buhari yẹ lẹ́ni tó yẹ ká gbé òṣùbà fún lórí àwọn ohun améyérọrùn - Oluwo
Ta ni Tafa Oloyede?
John Adewumi ni orúkọ tí ìyá àti bàbá rẹ̀ sọ ṣùgbọ́n orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ni Tafa Oloyede.
Ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kọkànlá ọdún 1952 ni wọ́n bi, tó sì bẹ̀rẹ̀ eré tíátà lọ́dún 1974.
Ọmọ bíbí ìlú Ẹdẹ ní ìpínlẹ̀ Osun ni, tó sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní ìpínlẹ̀ Osun.
Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bíi Jayesinmi, Ayanmo, Ekuro Oloja, Orogun, Akanji Oniposi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.














