Teenagers arrested for money ritual: 'Orí Facebook ni mo ti kọ́ nípa òògùn owó táà gé orí Sofiat fún ní Abeokuta'

Sofiat ati awọn afurasi to pa a

Oríṣun àwòrán, others

Ọkan ninu awọn ọmọkunrin to fi ọmọbinrin kan ṣoogun owo nilu Abeokuta, ti jẹwọ pe ori ayelujara Facebook ni oun ti kọ nipa oogun owo.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Abeokuta, Balogun Mustaqim to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun sọ pe ọsẹ meji ni awọn fi ṣe igbaradi fun fifi Rofiat Kehinde ṣe oogun owo.

O ni oun lo n kọkọ fẹ Rofiat ni ọdun 2021, ṣugbọn oun tun gba ki Soliu naa fẹ lẹyin ti awọn ko fẹ ara mọ.

Kiakia naa si ni Sofiat naa gba lati fẹ Soliu.

Bawo ni wọn ṣe gbeero oogun owo?

Gẹgẹ bi nkan ti afurasi akọkọ, Mustakeem sọ, Soliu lo mu àbá wa pe ki wọn o fi ọmọbinrin naa ṣe oogun owo, lẹyin ọsẹ diẹ to bẹrẹ si ni fẹ.

O sọ pe oju opo Facebook kan ti wọn ti n sọ nipa "Aṣiri awọn oogun oṣolẹ (oogun owo) to daju ni oun ti kọ bi awọn yoo ṣe ṣe e.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke

O ni lootọ Soliu lo fẹ ẹ lo Sofiat, ṣugbọn awọn jọ da owo ra awọn eroja ti wọn fẹ lo ni.

Ile ti Soliu n gbe ni Oke Aregba nilu Abeokuta ni wọn ti pa ọmọbinrin naa.

Àkọlé fídíò, Alhaji Shanko

Bawo ni Sofiat Kehinde ṣe fi ẹsẹ ara rẹ rin lọ ba iku ojiji?

Ni alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2022, ti wọn pa Sofiat, Soliu pe e lori ẹrọ ibanisọrọ pe ko wa si ile oun.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ

Bi ọmọbinrin naa ṣe de ibẹ, wọn jọ ni ibalopọ.

Lẹyin naa lo pe Mustaqim wọle fun iṣẹ ibi ti wọn fẹẹ sẹ.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

"Emi ni mo kọkọ n fi ọbẹ ge ni ori, ṣugbọn nigba ti ori naa ko tete gé jabọ, soliu fi ọwọ yin ọrun rẹ to fi ku.

"Nigba ti a pa a tan, Soliu sọ pe ki n ko ẹran ara rẹ yooku sinu apo, nitori pe oun ko le fi ọwọ kan lẹyin ibalopọ ki oogun owo naa ba le jẹ."

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà

Majekodunmi Soliu sọ pe Mustakeem lo mu àbá oogun owo wa

Ninu ọrọ ti Majekodunmi Soliu sọ, o ni Mustaqim lo daba pe ki awọn fi ọmọbinrin naa ṣe oogun owo, nitori pe kii ṣe ọmọ to ni laari lasiko ti awọn fi n fẹra.

"Mustaqim kii wa si ile mi tẹlẹ, ṣugbọn lati igba to ti n gbero pe ka lo Sofiat lo ti n wa si ile mi ni gbogbo opin ọsẹ.

Àkọlé fídíò, Eba

"To ba ti de, yoo sọ pe ki n pe ọmọ naa ko wa. Ṣugbọn mo ma n fi ọgbọn sọ fun ọmọbinrin naa pe mi o si nile.

O ni agidi ni Sofiat fi wa si ile oun ni ọjọ Ẹti to kọja lẹyin ọpọlọpọ igba ti oun ko jẹ ko wa nitori imọran Mustaqim.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Lẹyin ni ibalopọ pẹlu rẹ tan ni wọn pa a, ge ori ati itan rẹ, ki wọn o to ko iyoku ara rẹ sinu apo ti wọn gbe sọnu.

Ọpẹlọpẹ awọn ọdẹ adugbo to fura si nkan ti wọn n ṣe nile awọn ọmọkunrin meji yooku ti wọn ti lọ jo ori Sofiat, lo jẹ ki ọwọ ọlọpaa tẹ wọn.

'Orí Facebook ni mo ti kọ́ nípa òògùn owó táà gé orí Sofiat fún ní Abeokuta'

Ka ni wọn ṣe aṣeyọri ni, miliki ni wọn o fi ma a mu ẹbu ti wọn ri lara ori naa, pẹli igbagbọ pe awọn yoo ni owo.

Ẹni ọdun mọkandinlogun ni eyi to dagba ju lara awọn ọmọkunrin naa.

Gbogbo wọn lo ṣi wa ni ile ẹkọ girama.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere

Ẹgbọn Sofiat, Okeowo sọ fun akọroyin pe ounjẹ alẹ ni aburo oun n se lọwọ to fi tọrọ aaye pe oun fẹ de ibi kan.

Ṣugbọn iroyin pe wọn ti pa a ni awọn gbọ ni ọjọ keji, lẹyin ti wọn ti n wa lati alẹ ọjọ Ẹti

Àkọlé fídíò, Olùdíje gómìnà APC

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe nkan to sẹni laanu ni pe awọn ere ori itage ati ẹrọ ayelujara n kọ awọn ọdọ ni nkan ti ko dara.

Bakan naa lo ni awọn obi kan kii mojuto ọmọ wọn.

Àkọlé fídíò, Reminisce: Àwọn ọ̀dọ́ ló mọ ìtumọ̀ orin 'Problem'